Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Awọn ọlọpaa kogberegbe kan to wa ni ọfiisi awọn ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ni wọn doju ija kọ awọn janduku oloṣelu kan ti wọn fẹẹ waa fina si ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla yii.
Gẹgẹ bi awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣe sọ, wọn ni ni deede aago mẹrin idaji ọjọ Furaidee, ni awọn janduku naa fọ ogiri ileegbimọ aṣofin naa, ti wọn si fi epo bẹntiroolu wọn abala kan nibẹ lati fi ina si i.
Ti ẹ ko ba gbagbe, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni rogbodiyan bẹ silẹ ni kete ti awọn aṣofin yii dibo yan Ọnarebu Gboyega Aribisọgan, gẹgẹ bii abẹnugan ile naa lati rọpo Oloogbe Funminiyi Afuyẹ to jẹ Ọlọrun ni pe lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022.
Ninu ibo naa ti wọn di ni gbagede ile yii, Ọnarebu Gboyega Aribisọgan ni ibo mẹẹẹdogun, o fẹyin aṣofin to n ṣoju ijọba ibilẹ Emure, Ọnarebu Olubunmi Adelugba, to ni ibo mẹwaa janlẹ.
Lati ọjọ naa ni rogbodiyan ati aigbọra ẹni ye ti bẹ silẹ laarin awọn aṣofin naa, eleyii to kan awọn agbaagba ninu ẹgbẹ Onigbaalẹ ipinlẹ Ekiti tinu wọn ko dunu si bi Ọnarebu Adelugba ṣe padanu ipo abẹnugan naa.
Eyi lo fa a ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Moronkeji Adesina, ṣe paṣẹ pe ki wọn ti ile naa pa, to si tun paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa wa si agbegbe ati ayika ile naa lati daabo bo ayika ile ọhun.
Nigba to n sọrọ nipa bi awọn janduku oloṣelu kan ṣe fẹẹ fi ina si abala kan nileegbimọ naa, Alukoro ọlọpaa Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe awọn janduku bii mẹwaa ni wọn gbe epo bẹntiroolu to to bii lita marundinlọgbọn dani, ti wọn si gbiyanju lati fi ina si abala kan ni ile naa.
O ni awọn agbofinro ile naa ni ko jẹ ki wọn fi ina sile ọhun, ti wọn si le wọn wọ inu igbo kekere kan to wa ni agbegbe ile naa.
“Mo fẹẹ sọ fun yin pe awọn janduku naa gbe rọba epo meji dani wa si ileegbimọ lati waa ṣe ijamba, bakan naa ni wọn ko ada ati oun ija miiran dani.”
“Ohun ti wọn ro ni pe awọn ọlọpaa ti kuro ni agbegbe naa, nitori pe a ti ko ọkọ kuro ni agbegbe naa.”