Awọn janduku ja ile ẹru l’Apapa, gbogbo ounjẹ COVID-19 ni wọn n ko sa lọ

Faith Adebọla, Eko

Lati afẹmọjumọ Ọjọbọ, Tọsidee yii, lawọn janduku kan ti ja ile ẹru nla to wa ni Benster Cresent, tawọn eeyan mọ si Monkey Village, lagbegbe Mazamaza, nijọba ibilẹ Onidagbasoke Oriade, l’Ekoo, gbogbo ẹru tijọba ko pamọ sibẹ lawọn ọmọ ganfe naa ṣuru bo, wọn ha a fawọn eeyan, wọn si ko iyooku sa lọ.

Gẹgẹ bi ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣe sọ f’ALAROYE, o ni niṣe lawọn ẹruuku naa kọkọ dana saarin titi, wọn n sun taya lawọn ọna to wọ adugbo ti ile ẹru (warehouse) naa wa, boya kawọn agbofinro ma baa tete ka wọn mọ ibẹ, tabi kawọn eeyan le ro pe iwọde lasan lo n ṣẹlẹ ni.

O ni ko pẹ lẹyin naa lawọn gbọ tawọn janduku naa bẹrẹ si i pariwo pe kawọn araadugbo naa maa waa gba irẹsi ati ororo, nigba tawọn eeyan si de ibẹ loootọ, niṣe ni wọn n ha irẹsi, ororo, ẹwa, sẹmo atawọn ohun tẹnu n jẹ mi-in fun wọn lapo lapo, kẹtikẹti lawọn eeyan naa si n ko o.

ALAROYE gbọ pe ko si agbofinro to yọju sibi iṣẹlẹ yii, tori awọn janduku naa mu ibọn atawọn nnkan ija oloro mi-in lọwọ.

Leave a Reply