Awọn janduku ji eeyan mejidinlogun gbe lẹẹkan ṣoṣo lọna Eruwa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn ajinigbe gbọna ara yọ lọjọ kọkanlelogun, oṣu keji, ọdun 2021 yii, ti i ṣe Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, pẹlu bi wọn ṣe ji odidi eeyan mejidinlogun (18) gbe papọ lẹẹkan ṣoṣo.

ALAROYE gbọ pe arinrin-ajo ni gbogbo wọn, inu ọkọ bọọsi kan naa ni wọn wa ti awọn awodi ti ki i gbe adiẹ, afeeyan, fi ji gbogbo wọn gbe.

Nigba to ku diẹ ki wọn de ilu Eruwa lati Igboọra lawọn janduku ọhun bẹ siwaju mọto lojiji lati inu igbo.

Awọn arinrin-ajo yii ko mọ oju ti wọn fi sare sọ kalẹ ninu mọto nigba tawọn ẹruuku ọhun duro yika ọkọ wọn, ti wọn si na ibọn si wọn pe ki wọn sọ kalẹ kiakia.

Lẹyin ti awọn ero inu ọkọ yii sọ kalẹ pẹlu ibẹru-bojo tan lawọn ajinigbe ọhun fi gbogbo wọn si aarin, ti wọn si ko wọn lọ sinu igbo.

Ko sẹni to ti i gburoo ẹnikẹni ninu awọn mejeejidinlogun titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Leave a Reply