Monisọla Saka
Alaga ajọ eleto idibo ilẹ wa (INEC), Mahmood Yakubu, ti ṣalaye awọn adojukọ ti wọn ri lasiko ti eto idibo n lọ lọw yii. O ni pẹlu gbogbo eto ati ipalẹmọ ti awọn ṣe ṣaaju akoko yii, ọkunrin naa ni awọn gidigannku kan ti ko sẹni to mọ ibi ti wọn ti wa, tabi eeyan to ran wọn, ti ji ẹrọ BVAS, ti wọn fi n ṣayẹwo awọn oludibo gbe lọ nipinlẹ Katsina ati Delta.
Yakubu sọrọ yii nibi ti wọn ti n ṣakojọ ibo tawọn eeyan di niluu Abuja lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii. O ni oriṣiiriṣii idojukọ lawọn ti ri kaakiri orilẹ-ede yii, titi kan ọrọ igbokegbodo ọkọ to n ko awọn ohun eelo idibo ti wọn n ni ijamba atawọn mi-in ti wọn ko tete de latari ohun kan tabi omi-in, ati ọrọ eto aabo lọlọkan-o-jọkan ti ko fara rọ.
Yakubu ni pupọ awọn agbegbe jake-jado orilẹ-ede yii, ni ẹrọ BVAS ọhun ti ṣiṣẹ daadaa, ati pe awọn ibi perete kan ni wọn ti ni idiwọ lori bo ṣe n ṣiṣẹ mọnamọna. O tun fi kun un pe lara awọn wahala mi-in tawọn tun ni ni bi awọn oṣiṣẹ eleto idibo ko ṣe ri ibudo idibo de si laago mẹjọ aabọ aarọ to yẹ ki wọn ti wa nibẹ, latari wahala mọto, pẹlu gbogbo igbiyanju tawọn ti ṣe lori ọrọ naa.
O tẹsiwaju pe ẹrọ BVAS meji ni wọn ji gbe sa lọ, lasiko ti wọn kọ lu ibudo idibo kan ni Oshimili, nipinlẹ Delta. Ṣugbọn o ni kiakia ni ajọ INEC ti fi ẹrọ meji mi-in rọpo, ti wọn si wa nnkan ṣe si ọrọ eto aabo, wọn si tun ri i daju pe ibo didi tun tẹsiwaju pada.
Bakan naa lọrọ tun ri nijọba ibilẹ Safana, nipinlẹ Katsina. Nibi tawọn janduku ti kọ lu awọn ibudo idibo kaakiri, ti wọn si ji ẹrọ BVAS mẹfa gbe lọ, amọ tawọn oṣiṣẹ eleto idibo ti wọn wa nibẹ lo awọn ẹrọ mi-in dipo eyi ti wọn ji gbe lọ, wọn wa nnkan ṣe sọrọ eto aabo lati pada bọ sipo, wọn si tun bẹrẹ si i dibo wọn lọ pada.
Awọn oṣiṣẹ eleto aabo ti ri mẹta gba ninu awọn ẹrọ BVAS ti wọn gbe lọ yii, mẹta mi-in ṣi wa lọwọ awọn ẹni ibi ẹda ọhun.
Yakubu sọ siwaju si i pe ki i ṣe ike ti wọn n ju beba ti wọn fi dibo si ni wọn tori ẹ wa, bi ko ṣe ẹrọ BVAS yẹn gangan lohun ti wọn foju sun. O loun nigbagbọ pe laarin akoko perete to ku ki eto idibo fi wa sopin, ohun gbogbo yoo lọ nirọwọ-rọsẹ lai fi ti gbogbo wahala tawọn ti n koju bọ ṣe.