Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ori lo ko oludije fun ipo gomina ninu eto idibo to n bọ ninu ẹgbẹ SDP, Oloye Ṣẹgun Oni, yọ ninu iku ojiji nigba ti awọn janduku kan ti wọn ko ti i mọ ṣadeede ṣe akọlu si ọkọ ipolongo rẹ ni Efon-Alaye.
Lasiko akọlu naa to waye fun bii ọgbọn iṣẹju, ọpọlọpọ awọn alatilẹyin rẹ ati awọn ẹṣọ rẹ lo fara pa yannayanna. Bakan naa ni awọn oloye ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Ekiti fara pa ninu akọlu naa.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe ipolongo rẹ Ogbeni Jackson Adebayọ, fi sita lo ti ṣalaye oludije ẹgbẹ SDP naa ti ṣabẹwo si ijọba ibilẹ mẹsan-an ni ipinlẹ naa, ti ọgọọrọ awọn ọmọ ipinlẹ naa si ti n jade, ti wọn n gba oludije naa tọwọ tẹsẹ, ti awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ati APC si n darapọ mọ wọn.
O ni lojiji ni awọn janduku kan ya bo wọn ni deede aago mẹta aabọ ọsan ni ilu Ẹfọn-Alaye pẹlu ibọn lọwọ ati ada, ti wọn si bẹrẹ si i doju ija kọ awọn ọmọ ẹgbẹ Ẹleṣin naa.
O sọ pe awọn ololufẹ Ṣẹgun Oni atawọn ọmọ ẹgbẹ SDP ti wa ni gbọngan igbafẹ kan niluu naa ti wọn n duro de awọn agba ẹgbẹ yii lati ki wọn kaabọ, lasiko naa ni awọn janduku yii bẹrẹ si i yinbọn soke, eyi to fa a ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ SPD fi bẹrẹ si i sare kiri, eyi to mu ki ọpọ fara pa.
Niṣe ni wọn ba ọkọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa jẹ, lẹyin iṣẹju diẹ ni awọn ọlọpaa de, ti wọn si pẹtu si wahala naa.
Nigba to n sọrọ lori ikọlu naa, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe loootọ ni oun ti gbọ nipa akọlu naa.
Abutu ṣalaye pe awọn janduku ọhun ti wọn n ṣiṣẹ fun awọn oloṣelu kan ni wọn sadeede ya bo gbọngan ti wọn ti n ṣe eto ipolongo ti Ṣẹgun Oni n ṣe lọwọ.
O ni awọn ti bẹrẹ iwadi lori akọlu naa, o ṣeleri pe ọwọ yoo tẹ awọn to ṣiṣẹ buruku naa.