Awọn janduku kọ lu aafin Ṣọun Ogbomọṣọ, wọn ba dukia jẹ, wọn tun ṣe ijoye le ṣe

Ọlawale Ajao, Ibadan
Nnkan ko rọgbọ laafin Ṣọun ilẹ Ogbomọṣọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pẹlu bi awọn janduku kan ṣe ṣigun wọle sibẹ, ti wọn si ba ọpọlọpọ nnkan jẹ, ti wọn tun ko awọn dukia iyebiye kan lọ ninu aafin ọhun.
Iyẹn nikan kọ, ALAROYE gbọ pe wọn tun lu Arẹmọle ilẹ Ogbomọṣọ ti i ṣe ọkan ninu awọn ijoye ilu naa ṣe leṣe.
Bakan naa la gbọ pe wọn ji ade atawọn nnkan iṣẹnbaye kan ko ninu afin naa, ti wọn si tun ba ilẹkun abawọle, ferese atawọn dukia mi-in nibẹ jẹ.
Ṣugbọn nigba to n fidi iroyin yii mulẹ, Akọwe aafin Ṣọun, Ọgbẹni Toyin Ajamu, sọ pe wọn ko ri ade ọba ilu naa ji gbe lọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Loootọ ni wọn kọ lu aafin. Ṣugbọn wọn ko ji nnkan kan. Ko si ọba lori itẹ debi ti wọn yoo ri ade ji gbe. Wọn kan ba ilẹkun abawọle atawọn ilẹkun ti wọn maa n wọ sẹgbẹẹ jẹ ni. Bakan naa ni wọn ba ilẹkun ọfiisi inu aafin jẹ.”
Tẹ o ba gbagbe, lati inu oṣu Kejila, ọdun 2021, ni Ṣọun ilẹ Ogbomọṣọ, Ọba Jimoh Oyewumi, ti waja, ṣugbọn ti ọrọ ati fi ẹlomi-in jọba ko ti i lojutuu titi di ba a ṣe n sọ yii.

Leave a Reply