Awọn janduku kọ lu ile Sunday Igboho n’Ibadan

Adewumi Adegoke

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii ni ariwo gba ilu kan pe awọn janduku kan kọ lu ile ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo ẹeeyan mọ si Sunday Igboho, to wa ni Soka, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

ALAROYE gbọ pe niṣe ni awọn eeyan naa naa ya bo ibẹ pẹlu ibọn ati awọn ohun ija oloro mi-in. Bi wọn ṣe debẹ ni wọn kọju ija si awọn ọmọ Igboho to wa ninu ile ọhun, ki awọn eeyan naa si too mohun to n ṣẹlẹ, wọn ti pa ọkan ninu wọn, bẹẹ ni wọn ṣe awọn mi-in leṣe.

Ko ti i sẹni to le sọ ohun to fa a ti wọn fi kọ lu ile ọkunrin naa atawọn eeyan to wa nidii akọlu ọhun.

Ọkan ninu awọn ọmọọṣe Igboho, Ọnaọlapọ Omiyale, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu fọnran to gbe jade lori ẹrọ ayelujara. Bakan naa ni agbẹjọro rẹ, Yọmi Alliyu, naa fidi rẹ mulẹ pe loootọ lawọn janduku kan ya wọn ile ọkunrin naa. O ni nibi ti awọn ọmọlẹyin rẹ to wa ninu ile ọhun ti doju ija kọ wọn ki wọn ma le raaye wọle ni wọn ti pa ọkan ninu wọn, ti wọn si ṣe ọpọ wọn leṣe.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun to kọja, ni awọn ọtẹlẹmuyẹ ya bo ile ọkunrin naa, ti wọn si pa awọn ọmọọṣẹ rẹ meji lasiko ikọlu ọhun. Bẹẹ ni wọn ba ọpọlọpọ dukia jẹ nile rẹ.

Asiko ti ọkunrin naa fẹẹ yẹra ni Naijiria to n mura lati lọ siluu oyinbo ni wọn mu un, ti wọn si fi i sahaamọ ọgba ẹwọn ni orileede Benne, nibi to wa titi di ba a ṣe n sọ yii.

Leave a Reply