Awọn janduku kọ lu ileeṣẹ Saraki n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Alẹ ọjọ Ẹti, Furaide, niroyin gba igboro pe awọn janduku kan kọ lu ileeṣẹ iwe iroyin National Pilot to wa lọna Asa Dam, niluu Ilọrin, ti wọn si ba awọn nnkan jẹ nibẹ.

ALAROYE gbọ pe ori lo ko Olootu agba iwe iroyin naa, Billy Adedamọla, atawọn oṣiṣẹ rẹ yọ nitori bi iṣẹlẹ naa ṣe ka wọn mọ ọfiisi.

Ṣe lawọn janduku ọhun fọ awọn ferese to wa lara ile naa ati ina mọnamọna ti wọn ṣe sinu ọgba.

Lẹyin ti wọn fọ awọn ferese ile naa ni wọn dana siwaju ibẹ ko too di pe wọn kuro.

Adedamọla to fidi rẹ mulẹ ṣalaye pe nigba toun ṣakiyesi pe ita ti n gboro, oun fi mọto ko awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa jade kuro nibẹ ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ.

O ni ẹyin lawọn gba jade tawọn fi mori bọ lọwọ awọn janduku naa. O dupẹ pe ko si ẹnikan kan ninu awọn to fara pa.

 

Olori ile-igbimọ aṣofin agba tẹlẹ, Dokita Abubakar Bukọla Saraki lo ni ileeṣẹ iwe iroyin National Pilot.

Leave a Reply