Awọn janduku kọ lu oloye ẹgbẹ APC meji nibi ipade kan ni Lafiagi

Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọrọ di bo o lọ o yago lọna lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nigba tawọn janduku kan yabo adari ẹgbẹ APC meji nipinlẹ Kwara; Alhaji Tajudeen Abdulkadir Audu ati Alhaji Shuaibu Yaman Abdullahi, lasiko ipade kan to waye niluu Lafiagi, nijọba ibilẹ Edu, nipinlẹ Kwara.
ALAROYE gbọ pe ṣe lawọn janduku naa fọ gilaasi ọkọ jiipu ti ọkan lara wọn gbe wa sibẹ.
Ohun tawọn eeyan sọ ni pe, ija abẹle to n ṣẹlẹ laarin Gomina Abdulrahman Abdulrazaq atawọn to n ṣe atilẹyin fun alaga APC ti wọn yẹ aga mọ nidii laipẹ yii, Bashir Ọmọlaja Bọlarinwa, ninu ẹyi ti Minisita feto iroyin ati aṣa, Alhaji Lai Mohammed, Akọgun Iyiọla Oyedepo, atawọn mi-in bẹẹ lọ wa, lo ṣokunfa akọlu naa.
Ṣe lọsẹ to kọja lawọn igun mejeeji fija fẹẹta nibi ipade to waye ninu gbọngan nla ‘Banquet Hall’ to wa nidojukọ ile ijọba, niluu Ilọrin.
Bawọn kan ṣe n sọrọ buruku sira wọn bẹẹ lawọn mi-in n ju aga lu ara wọn lọjọ naa. O kere ju eeyan bii mẹwaa lo farapa nibi iṣẹlẹ naa.
Akọroyin wa gbọ pe ipade ti n lọ lọwọ lọjọ Aje ko too di pe awọn janduku kan yawọ inu ọgba ti wọn ti n ṣepade naa.
Bi wọn ṣe debẹ ni wọn bẹrẹ si ni pede oriṣiriiṣi bi i tawọn ọmọọta ti wọn si ba nnkan jẹ.
Lati bi i ọsẹ kan sẹyin ni nnkan ko ti fararọ lẹgbẹ APC, paapaa latigba tẹgbẹ ti kede igbakeji alaga APC, Abdullahi Samari, gẹgẹ bi i alaga igbimọ alamojuto ẹgbẹ.
Bawọn kan ṣe n ṣe atilẹyin fun Bọlarinwa ti wọn yọ nipo bẹẹ lawọn kan n gbe Samari lẹyin.

Leave a Reply