Awọn janduku mura bii fijilante, wọn bẹ sikiọriti lori, wọn dana sunle kọmiṣanna eto idajọ tẹlẹ

Eto aabo to polukurumuṣu lapa Ila-Oorun ilẹ wa, iyẹn ilẹ Ibo, tun gba ọna mi-in yọ l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, nipinlẹ Imo, niṣe lawọn janduku ẹda kan mura bii ẹṣọ fijilante, ni wọn ba ya bo ile kọmiṣanna feto idajọ to ṣẹṣẹ kuro nipo, Oloye Crypian Akaolisa, wọn bẹ sikiọriti to n sọ ọgba ile naa, wọn si dana sunle ọhun ati dukia to wa nibẹ raurau.

Ba a ṣe gbọ, ile awoṣifila ọhun to wa lagbegbe Ebenato, nijọba ibilẹ Orsu, nipinlẹ ọhun, lawọn janduku ti wọn dihamọra ogun pẹlu ibọn atawọn nnkan ija oloro dana sun, lẹyin ti wọn ti kọkọ yin bọmbu si i.

Wọn ni iro bọmbu to n dun gbau gbau leralera lagbegbe ọhun da ipaya gidi silẹ fawọn olugbe ibẹ, ọpọ wọn ko tilẹ le yọju sita waa wo ohun to n ṣẹlẹ, bẹẹ ni ko ṣee ṣe fun wọn lati sa lọ tori ko sẹni to mọ pato ibi ti iro buruku naa ti n ṣẹlẹ gan-an.

Ẹnikan tọrọ naa ṣoju rẹ sọ pe awọn n gbọ bi baba to n ṣe sikiọriti nile ọhun ṣe kigbe oro nigba tawọn janduku naa kọ lu u, ṣugbọn ko sẹni to laya lati yọju.

Oloye Akaolisa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun Ajọ akọroyinjọ ilẹ wa, NAN, o ni Ọlọrun lo yọ oun, jinnijinni da bo oun nigba toun gbọ ohun to ṣẹlẹ, toun si ri awoku ile naa ti wọn ti sọ ọ di eeru, o lo ya oun lẹnu pe eeyan le ronu iwa buruku bẹẹ si ẹda ẹgbẹ ẹ.

Bakan naa la tun gbọ pe awọn agbebọn mi-in tun ya bo ile Ọnarebu Ekene Nnodumele to n ṣoju agbegbe Orsu nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Imo, wọn si sọ ina sile ọhun to wa laduugbo Awo Idemili.

Oluranlọwọ pataki si aṣofin naa, Ọgbẹni A. Nwadikwa, sọ pe loootọ ni wọn dana sun ile ọga oun, ṣugbọn ina naa ko ka ẹnikẹni mọle, bo tilẹ jẹ pe gbogbo dukia ibẹ lo jona kanlẹ. O ni bi wọn ṣe sọna sile naa tan ni wọn ti sa lọ kawọn agbofinro too de.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Imo, Abutu Yaro, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ti bẹrẹ iwadii, awọn si ti da awọn ọtẹlẹmuyẹ sigboro lati tọpinpin awọn ọbayejẹ to ṣiṣẹ laabi ọhun.

Leave a Reply