Awọn janduku ya bo ile awọn oloṣelu l’Ọṣun, wọn n ba nnkan ini wọn jẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ti awọn araalu ti n ko ẹru Corvid-19 niluu Ẹdẹ lawọn janduku kan ti dara pọ mọ wọn.

Nidaaji ọjọ Abamẹta, Satide opin ọsẹ yii, ileeṣẹ Alhaji Tunde Badmus, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Tuns Farm ni wọn kọkọ lọ loju ọna Oṣogbo si Ikirun. Baba yii nijọba ipinlẹ Ọṣun fi ṣe alaga igbimọ ti yoo gba nnkan jọ latọdọ awọn to ba fẹẹ ran Ọṣun lọwọ lasiko korona.

Yatọ si pe baba yii gbe owo nla silẹ funra rẹ gẹgẹ bi awọn eeyan bii Pasitọ Adeboye, Pasitọ Aṣhimọlowo, Ọmọọba Oyinlọla, Oloye Alakija ati bẹẹ bẹẹ lọ ṣe ṣe, ọpọ ijọ lo tun fi tọju awọn agbofinro ti wọn ṣiṣẹ loju ọna nigba naa.

Iwadii fihan pe ijọba pada gba akoso awọn nnkan iranwọ korona yii lọwọ Alhaji Badmus, ṣugbọn ko sẹni to mọ.

Ibinu pe awọn eeyan ri ẹru korona l’Ẹdẹ ni wọn fi lọ sileeṣẹ baba naalọjọ Abamẹta, wọn ko fulawa to fi n ṣe burẹdi, wọn ko adiyẹ, wọn ko bisikiiti ti wọn n ṣe nibẹ, wọn gbe aga atawọn nnkan ọfiisi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bi wọn ṣe kuro nibẹ ni wọn tun lọ si ọfiisi ipolongo ibo igbakeji abẹnugan ile-igbimọ aṣofin apapọ orileede wa nigba kan, Lasun Yusuff, wọn ko gbogbo nnkan nibẹ. Wọn tun lọ sile rẹ niluu Ilobu.

Bakan naa ni wọn fọwọ kan sẹkiteriati ẹgbẹ oṣelu APC, ọfiisi ipolongo ibo gomina, ṣekiteriati ijọba ibilẹ Iwo, sẹkiteriati ijọba ibilẹ Ifẹlodun, ile awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin Ọṣun.

Lọwọlọwọ bayii, wọn ko ti i dawọ duro, wọn ṣi n lọ kaakiri ile kan si omi-in.

Leave a Reply