Awọn janduku ya wọ ileewe ẹkọṣẹ iṣegun UNIOSUN, wọn fẹẹ gbe oku lai ṣe akọsilẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ere aṣapajude ni gbogbo awọn ti wọn wa ninu ileewe ẹkọṣẹ iṣegun Ọṣun State University Teaching Hospital, niluu Oṣogbo, sa lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, nigba ti awọn janduku kan ya wọbẹ lati fi dandan gbe oku ọkan lara wọn to wa nile igbokusi.
Awọn janduku naa la gbọ pe wọn lọ sibẹ pẹlu oriṣiiriṣii ọkada, ti wọn si n pariwo pe ki awọn alaṣẹ ọsibitu naa gbe oku ti awọn kan gbe wa silẹ lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, jade fun awọn.
Nigba ti ọkan lara awọn oṣiṣẹ ọsibitu naa yọju si wọn, to si ṣalaye pe awọn akọsilẹ kan wa ti wọn gbọdọ ṣe ko too di pe wọn aa gbe oku, ni wahala bẹ silẹ, ti awọn tọọgi naa si fariga.
Bi wọn ṣe n fa olonde jade nibadi, ni wọn n mu oogun abẹnugọngọ jade lapo, ti wọn si n leri pe ẹni ti ko ra yoo san ninu rẹ ti awọn ba ṣina wahala silẹ lọsibitu naa.
Kia ni gbogbo agbegbe naa ti da paroparo, awọn oṣiṣẹ pẹlu awọn ti wọn jẹ mọlẹbi awọn ti wọn n gbatọju lọwọ nileewosan ti wa ibikan fi ori wọn pamọ si nitori ariwo naa pọ pupọ.
A gbọ pe nigba ti oniruuru awọn oṣiṣẹ alaabo debi iṣẹlẹ naa ni wọn to lanfaani lati le awọn tọọgi naa jade, ti alaafia si pada sagbegbe naa.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, alaga igbimọ to n gba ọsibitu naa nimọran (Medical Advisory Committee), Dokita Babatunde Afọlabi, sọ pe wọn ti yanju wahala naa, ati pe wọn ti pada ṣe ohun to tọ lori oku naa ki wọn to gbe e lọ.

Leave a Reply