Awọn kan lọọ yọ geeti abawọle ileewe C&S n’Ilọrin loru

 

Loruganjọ ni awọn kan lọwọ yọ geeti ileewe girama C&S, to wa ni Saabo-Oke, nìyi Ìlọrin bọ sile látàrí bi awọn aláṣẹ ileewe naa ko ṣe faaye gba awọn akẹ́kọ̀ọ́ to lo hijaabu lati wọ ileewe naa.

Awọn tiṣelẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe nnkan bii aago kan oru ni ọkọ jiipu Hilux funfun kan pẹlu awọn eeyan ti wọn fura si pe wọn n ba ijọba ṣiṣẹ, ya bo ileewe C & S to wa ni Sabo-Oke, niluu Ilọrin, ti wọn si yọ geeti ileewe naa lọ patapata.

Ileewe ọhun wa lara awọn ibi ti wọn ti n fa wahala hijaabu.

Iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lẹyin wakati diẹ ti Gomina Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq ba araalu sọrọ lati gba alaafia laaye.

 

 

Leave a Reply