Awọn kan ninu awọn akẹkọọ ti wọn ji ko ni Katsina lawọn ko ni i pada sileewe mọ

Jide Alabi

Bi inu obi awọn ọmọ Hausa ti awọn janduku ajinigbe kan ji gbe ṣe n dun pe wọn ti gba itusilẹ, bẹẹ lawọn ọmọ naa ti n ba awọn oniroyin sọrọ nipa ohun ti oju wọn ri fun odidi ọjọ mẹfa lakata awọn ajinigbe.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja lọhun-un, lawọn ajinigbe ya wọ ileewe kan to n jẹ Government Science Secondary School, ni Kankara, nipinlẹ Katsina, ṣugbọn ni bayii, gbogbo wọn pata ti iye wọn jẹ ọọdunrun ati mẹrinlelogoji (344) ni wọn ti gba itusilẹ.

Oriṣiiriṣii iriri lawọn ọmọ ọhun n sọ bayii nipa ohun ti oju wọn ri, bẹẹ ni wọn sọ pe irọ lawọn eeyan ọhun pa, wọn ki i ṣe Boko Haram, ati pe nigba ti awọn ri i bi awọn ẹṣọ agbofinro ọhun ṣe n rọjo ibọn lu awọn lati oju ofurufu lo jẹ kawọn pe wọn ni Boko Haram.

Ọkan ninu awọn ọmọ naa sọ pe pẹlu ibẹru-bojo lọkan ninu wọn fi ni ki oun sare ṣe fidio pe ti awọn ẹṣọ ọhun ko ba dawọ ibọn ti wọn n yin duro, pipa lawọn yoo pa gbogbo awọn danu.

Farouq Aminu ninu ọrọ tiẹ sọ pe, “Bi mo ṣe n sọrọ yii, ara mi ko ti i balẹ rara, mo nilo alaafia gidi, ọpọ maili lawọn ajinigbe yii fipa mu wa rin, bẹẹ ni wọn tun fiya jẹ awọn kan ninu wa ti irin wọn ko ya kanmọ-kanmọ bii tiwọn. Odunkun ni wọn fun wa jẹ ati ẹgẹ, bẹẹ ki i ṣe ojoojumọ la n jẹun, iya buruku ni wọn fi jẹ wa, bẹẹ lawọn mi-in ninu wa ri awọn eeso jẹ pẹlu.’’

Ọmọ yii fi kun un pe oun ko gbọ pe ẹnikẹni ku ninu awọn. O ni bi wọn ṣe tu awọn silẹ, wọn kọkọ ko awọn lọ si ibi kan nipinlẹ Zamfara, iyẹn Tsafe, ko too di pe wọn ko awọn wa si Katsina.

Abubakar Sodiq sọ ni tiẹ pe ni kete ti wọn ti ji awọn gbe ni wahala ọhun ti bẹrẹ, bi wọn ṣe n yinbọn soke ni wọn n kilọ fawọn pe awọn ko waa ṣere o, ẹni to ba fẹẹ ṣe bii akọni laarin awọn, iku ni o.

‘‘Igba to ba wu wọn ni wọn n fun wa lounjẹ, bẹẹ omi to dọti patapata ni wọn tun n fun wa mu pẹlu. Eyi gan-an lo ṣokunfa bi awọn kan ninu wa ṣe dubulẹ aisan, emi paapaa, ara mi ko ya rara, mo fẹẹ lọ sile.”

Yusuf Sulaiman ninu ọrọ tiẹ sọ pe eto aabo ti ko munadoko to nileewe awọn lo fa a ti awọn janduku ajinigbe ọhun ṣe raaye wọle, ti wọn si ji awọn gbe. Ọmọ yii ti sọ fawọn oniroyin pe ko daju pe oun yoo tun pada sileewe ọhun mọ, nitori ko si aabo gidi kan bayii nibẹ.

Yatọ si eyi, ọkan lara awọn ọmọ ti wọn tu silẹ yii to wa ninu fidio ti awọn to ji wọn gbe fi sita sọ pe niṣe ni wọn fipa mu oun ki oun sọ pe awọn Boko Haram ti Abubakar Shekau, gan-an lo ji awọn  gbe.

Eyi ati ohun mi-in loriṣiiriṣii lawọn ọmọ naa n sọ, paapaa nipa iriri wọn. Bi awọn kan ninu wọn ṣe n sọ pe ko daju pe awọn yoo pada sileewe ọhun mọ, bẹẹ lawọn mi-in paapaa n sọ pe ohun ti oju awọn ri ki i ṣe ohun to rọju rara.

Tẹ o ba gbagbe, Sultan ilu Sokoto paapaa ti sọ pe wahala tawọn janduku ajinigbe atawọn Boko Haram n ko ba agbegbe awọn, bii ẹni mọ-ọn-mọ fẹẹ ṣakoba fun ọjọ ọla awọn ti awọn jẹ Hausa ni, nitori iru iṣẹlẹ bẹẹ yoo mu awọn obi ma ran ọmọ lọ sileewe mọ, bẹẹ lawọn ọmọ paapaa le tori ibẹru maa sa nileewe.

Leave a Reply