Awọn kan ti n da ẹru ti wọn ji ko pada fun ijọba l’Edẹ  

Jide Kazeem

Laduugbo kan ti wọn pe ni Unit One, l’Owode, niluu Ẹdẹ, ipinlẹ Ọṣun, lawọn eeyan ti n da ẹru ti wọn ji ko pada lasiko rogbodiyan to bẹ silẹ lọsẹ to kọja.

Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe ni kete ti ijọba ti kede pe ki awọn eeyan ilu da awọn ohun ti wọn ba ji ko pada laarin ọjọ mẹta lawọn eeyan ti gbọ ipe yii, ti awọn kan si ti n ru tiwọn pada bayii.

Ohun ti ijọba Ọṣun sọ ni pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pẹlu awọn ohun ti ijọba n wa yii, oju ẹlẹwọn loun yoo fi wo wọn, bẹẹ nirufẹ ẹni bẹẹ yoo faṣọ penpe roko ọba.

Leave a Reply