Awọn kan ti n lẹdi apo pọ lati gbajọba lọwọ Buhari o – Fẹmi Adeṣina

Faith Adebọla

 O jọ pe nnkan kan ti n rugbo bọ nileeṣẹ Aarẹ ilẹ wa lasiko yii, pẹlu bi wọn ṣe fẹsun kan awọn aṣaaju ẹsin atawọn oloṣelu ana kan tinu n bi, wọn lawọn ni wọn n lẹdi apo pọ pẹlu awọn ajoji kan lati orileede mi-in lati gbajọba lọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari.

Oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, sọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, pe awọn kan ti wọn ti sọ ara wọn di irinṣẹ idaluru ati agbẹyin-bẹbọ-jẹ ni wọn n gbero lati da yanpọnyanrin silẹ, o ni ki i ṣe pe ileeṣẹ Aarẹ n mefo lori ọrọ yii o, nnkan ti olobo to ṣee fọkan tẹ fihan fawọn ni.

Fẹmi ni: “Awọn ẹri ti ko ṣee jiyan rẹ ti tun fihan pe awọn adarugudu silẹ ẹda wọnyi ti n fa awọn olori ẹya kan loju mọra kaakiri orileede yii, pẹlu ero lati pe apero nla, nibi ti wọn ti maa kede pe Aarẹ Buhari ti ja awọn kulẹ, ijọba rẹ ti ja awọn kulẹ, wọn aa si ko orileede yii si yanpọnyanrin.

“Ọgbọnkọgbọn tawọn agbẹyin-bẹbọ-jẹ yii ko ri da lasiko eto idibo ọdun 2019 ni wọn fẹẹ gbọna ẹyin ṣe lati doju ijọba bolẹ.

Awọn aṣaaju ẹsin tinu n bi kan pẹlu awọn oloṣelu ana ni wọn n gbero lati sọ orileede yii sinu okunkun, eyi to le mu kawọn alagbara fipa gba ijọba, ki wọn si doju eto dẹmokiresi ati eto iṣakoso yii de. Awọn eeyan yii atawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ wọn ti n ba awọn eeyan kan sọrọ lorileede mi-in lati lo gbogbo agbara ti wọn ba ni lori Naijiria, ki wọn si le Buhari tawọn araalu dibo yan lati ṣakoso titi di ọdun 2023 danu lori aleefa.

“Awọn ọmọ Naijiria ti pinnu pe ijọba demokiresi lawọn fẹ, ko si sọna mi-in to bofin mu, to si ṣetẹwọgba, lati paarọ ijọba ju ki wọn dibo lọ, o si ti lasiko ti eto idibo maa waye. Ọna eyikeyii mi-in lati doju ijọba yii de ko le bofin mu, iwa ifipa gbajọba ni, ko si le bimọ ire.”

Leave a Reply

%d bloggers like this: