Awọn kọmiṣanna pẹlu awọn alaṣẹ eto ẹkọ fọwọ si idije imọ ede Yoruba laarin awọn akẹkọọ ileewe girama

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gbogbo kọmiṣanna feto ẹkọ atawọn to ni nnkan an ṣe pẹlu eto ẹkọ jake-jado ẹkun Iwọ-Oorun orile-ede yii (ilẹ Yoruba) ati Kwara pẹlu Kogi, ti fọwọ si idije imọ ede Yoruba ti yoo waye laipẹ yii laarin awọn akẹkọọ ileewe girama nilẹ Yoruba.

Ajọ Yoruba World Centre, pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ to jẹ ajumọni awọn ijọba ilẹ Yoruba, iyẹn Odu’a Investment Company Plc. ati DAWN Commission, iyẹn ajọ to n ri si eto idagbasoke ilẹ Yoruba lo gbe idije ọhun kalẹ fawọn akẹkọọ ileewe girama nilẹ Yoruba.

Afojusun awọn to gbe eto ọhun kalẹ gẹgẹ bi Ọgbẹni Alao Adedayọ ṣe fidi ẹ mulẹ, ni lati sọ awọn akẹkọọ to ba gbegba oroke ninu idije naa di miliọnia, ki wọn si pada soju ọna iye lẹyin ti wọn ti sọnu sinu aṣa awọn oyinbo; lati mu idagbasoke ba ede Yoruba, ati lati mu iṣọkan ba awọn ẹya orilede yii.

Nitori aṣeyọri eto idije ọhun, eyi ti wọn fẹẹ fi sọ awọn akẹkọọ to ba kopa ninu ẹ di miliọnia lawọn kọmiṣanna, ileeṣẹ atẹwe, onkọwe, olukọ ede Yoruba atawọn ti idagbasoke ede Yoruba jẹ logun, ṣe ṣepade n’Ibadan lopin ọsẹ to kọja.

Ileeṣẹ O’dua Group lo gbalejo ipade ọhun, eyi to waye ninu ile alaja mẹẹẹdọgbọn (25) nni, Coco-House, n’Ibadan, eyi ti ajọ DAWN Commission n ṣakoso le lori.

Kọmiṣanna feto ẹkọ nipinlẹ Ọyọ, Ọmọwe Abdurahman Abdu-Raheem, funra rẹ kopa ninu ipade ọhun, nigba ti awọn akẹgbẹ rẹ lati ipinlẹ Eko, Ogun ati Ondo ran aṣoju wa. Ọgbẹni Adebayọ Adeyẹmi ti i ṣe oludari awọn akanṣe iṣẹ ati ọgbọn atinuda fun ijọba ipinlẹ Eko lo ṣoju kọmiṣanna feto ẹkọ nipinlẹ naa. Oludari eto igbelarugẹ eto ẹkọ nipinlẹ Ogun, Abilekọ Bamidele Makinde, lo ṣoju kọmiṣanna feto ẹkọ nipinlẹ Ogun, nigba ti Abilekọ Tọla Adeniyi, oludari ọrọ gbogbo to ni i ṣe pẹlu awọn ileewe nipinlẹ Ondo ṣoju kọmiṣanna feto ẹkọ ni ipinlẹ naa.

Lara awọn to tun kopa ninu ipade pataki ọhun  ni Aarẹ Ẹgbẹ Akọmọlede ati Aṣa Yoruba, Aarẹ Ọmọwumi Falẹyẹ; Aarẹ ẹgbẹ YSAN (Yoruba Studies Association), iyẹn ẹgbẹ awọn onimọ ijinlẹ ede Yoruba, Ọjọgbọn Dele Orimogunjẹ ati Ọmọwe Adeọla Falẹyẹ ti i ṣe igbakeji rẹ; Aarẹ ẹgbẹ awọn olukọ ede Yoruba lawọn ile-ẹkọ kọlẹẹji, Ọmọwe Sọji Aderẹmi Fajẹnyọ

Awọn yooku ni Ọjọgbọn Adedọtun Ogundeji ti i ṣe alakooso Ibi Iṣẹ Ede Yoruba (Yoruba Language Centre) ni Fasiti Ibadan (UI); Ọjọgbọn Dele Layiwọla lati eka imọ nipa ilẹ Afirika ni Fasiti Ibadan, Abilekọ Labakẹ Owolabi, ẹni to ṣoju ajọ ti wọn n pe ni Centre for Yoruba Language Engineering (CEYOLENG), Ọmọwe Tunde Ọdunlade, to jẹ oludasilẹ Tunde Odunlade Arts Gallery; Abilekọ Fọlakẹmi Bademọsi, ẹni to ṣoju fun ileeṣẹ itẹwe University Press Limited ati Ọgbẹni Emmanuel Abimbọla ti i ṣe akọwe agba ẹgbẹ awọn ileeṣẹ to n tẹwe nilẹ yii.

Nigba to ki awọn olukopa kaabọ sibi ipade naa, oludari agba ajọ DAWN Commission, Ọgbẹni Ṣẹyẹ Oyelẹyẹ sọ pe asiko ti to wayi fun gbogbo ọmọ Yoruba lati fọwọsowọpọ lati

lati ko ede Yoruba yọ kuro loko iparun.

Ninu ọrọ tiẹ, Oludari agba ileeṣẹ O’dua Group, Ọgbẹni Adewale Raji, sọ pe idije imọ ti wọn tori ẹ ṣepade yii wa ni ibamu pẹlu erongba ileeṣẹ O’dua, nitori afojusun ileeṣẹ ọhun ni lati mu idagbasoke ba ilẹ Yoruba ni gbogbo ọna.

Ṣaaju, l’Ọgbẹni Adedayọ ti i ṣe olugbekalẹ ajọ Yoruba World Centre ti ṣalaye fawọn olukopa ninu ipade yii nipa idije imọ ọhun ti yoo waye laarin awọn akẹkọọ ileewe girama yii, ti wọn si jiroro lori ọna ti wọn yoo gba ṣeto naa laṣeyọri lẹyin ti gbogbo wọn ti fi tayọtayọ fọwọ si i.

Gẹgẹ bii abajade ipade ọhun, laipẹ laijina ni wọn yoo kede ọjọ ti idije to pa gbogbo ilẹ Yoruba ati ipinlẹ Kwara pẹlu ipinlẹ Kogi pọ yii yoo bẹrẹ.

Leave a Reply