Awọn meji ṣubu lori ọkada, lọkọ ba tẹ wọn pa l’Akungba Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọjọ ibanujẹ mi-in lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, tun jẹ fawọn eeyan ilu Akungba Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Naijiria, pẹlu bi ọkọ bọọsi kan ṣe tẹ eeyan meji pa lẹyin ti wọn ja bọ lori ọkada ti wọn wa lalẹ ọjọ naa.

Gẹgẹ ba a ṣe ṣe fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ẹnikan tiṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ, o ni awọn ọlọkada meji ni wọn kọkọ kọ lu ara wọn loju ọna marosẹ to gba aarin ilu kọja.

Ibi ti wọn ti n gbiyanju ati sare dide loju titi ti wọn subu si ni ọkọ elero mejidinlogun ọhun de ba wọn lojiji, to si tẹ wọn pa.

O ni ere asapajude tí awakọ yii n sa ni ko fi tete ṣakiyesi pe awọn eeyan kan ti ṣubu sori titi to fẹẹ gba kọja, ẹran ara ọkan lara awọn ọlọkada naa lo ni ọkọ pín yẹlẹyẹlẹ sì aarin ọna ibi to tẹ ẹ pa si.

 

 

Leave a Reply