Awọn mẹta dero ẹwọn, ori oku mẹwaa ni wọn ba lọwọ wọn 

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Awọn ọkunrin mẹta kan ti dero ọgba ẹwọn. Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni wọn foju bale-ẹjọ Majisreeti-agba to wa niluu Ado-Ekiti lori ẹsun pe wọn lọọ ge ori oku mẹwaa niboji.

Kọla Fatoye, ẹni ogoji ọdun pẹlu Abimbọla Fatoye toun jẹ ẹni ọdun mariundinlogoji ati Ahmed Ojo, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta, lawọn ọlọpaa sọ pe wọn huwa ọhun laarin oṣu kẹta si oṣu kẹsan-an, ọdun yii, niluu Ọrun-Ekiti.

Inspẹkitọ Monica Okebuilo ṣalaye pe laarin asiko naa lawọn olujẹjọ lọ si iboju ileejọsin St Paul’s Anglican Church, ti wọn si ge ori oku mẹwaa ọtọọtọ, bẹẹ ni wọn ko oogun abẹnugọngọ dani, wọn ko si ri alaye gidi kankan ṣe nigba tọwọ tẹ wọn.

O ni iwadii fi han pe ọdaran ni wọn, wọn si ti ṣe si ofin ijọba, eyi lo ṣe yẹ ki wọn jiya labẹ ofin.

O waa sọ ọ di mimọ pe oun ti fi ọrọ wọn lọ ẹka to n gba adájọ́ nimọran (DPP), fun igbesẹ to kan. O ni ki kootu fi awọn afurasi naa pamọ sọgba ẹwọn di igba ti DPP yoo sọrọ.

Leave a Reply