Awọn mẹta yii ja Tọpẹ Alabi lole owo nla

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Idigunjale lawọn gende mẹta yii, Aanu Ibikunle, Rasheed Bisiriyu ati Adebọwale Dada, yan laayo. Ohun ti wọn ṣe naa ree nigba ti wọn ko obinrin oniṣowo kan torukọ rẹ n jẹ Tọpẹ Alabi ni papamọra, ti wọn si gba owo nla lọwọ rẹ lọjọ kejilelogun, oṣu keje yii, lagbegbe Oke-Ore, Atan-Ọta, nipinlẹ Ogun.

Ipe ‘ẹ gba wa’ lo de etiigbọ DPO teṣan Atan-Ọta, CSP Abọlade Ọladigbolu, pe awọn adigunjale ti bo ṣọọbu obinrin oniwosiwosi ati nnkan mimu kan, wọn si ti gba owo nla lọwọ rẹ. Alẹ, ni nnkan bii aago mẹwaa ku iṣẹju mẹẹẹdogun si ni iṣẹlẹ naa n waye.

Awọn ọlọpaa lọ sibẹ lati mu awọn ole naa ṣinkun, ṣugbọn niṣe lawọn adigunjale yii doju ija kọ wọn, gẹgẹ bi Alukoro wọn, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe wi. Ṣugbọn nigba ti awọn ọlọpaa kọju ija si wọn bo ṣe yẹ ko ri, kia ni wọn mura ati sa lọ.

Nibi ti wọn ti fẹẹ fẹyin rin naa lawọn agbofinro ti mu awọn mẹtẹẹta, iyẹn Aanu; ẹni ọdun mejilelọgbọn,Rasheed; ẹni ọdun mejilelogun ati Adebọwale; ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn.

Lara awọn nnkan tawọn ọlọpaa ba lọwọ wọn ni ibọn ilewọ ibilẹ kan, ọta ibọn meji ti wọn ko ti i yin atawọn ogun ibilẹ loriṣiiriṣii.

Wọn ti ko wọn lọ sẹka itọpinpin to lagbara, ọga ọlọpaa CP Edward Ajogun si gba awọn araalu nimọran lati maa tete fi ohun to ba n ṣẹlẹ lagbegbe wọn to ọlọpaa leti, nitori nipa bẹẹ lọwọ yoo maa tẹ awọn oniṣẹẹbi.

Leave a Reply

%d bloggers like this: