Awọn minisita Naijiria ko sọrọ nipa bawọn ṣọja ṣe paayan l’Ekoo

Aderounmu Kazeem

Ohun ibanujẹ lo jẹ fun ọpọ ọmọ Naijiria, lana-an nigba tawọn igbimọ to n ba Aarẹ Buhari pari ipade wọn, ṣugbọn ti wọn ko sọ nnkankan fawọn oniroyin nipa ohun to ṣẹlẹ lagbegbe Lẹki.

Wọn ni, ni kete ti wọn pari ipade ti Aarẹ, maa n ṣe pẹlu awọn minisita rẹ, ko si eyikeyii ninu awọn to ba oniroyin sọrọ to fẹnukan ohun to ṣẹlẹ ni Lẹkki, l’Ekoo, nibi tawọn Ṣoja ti kọju ibọn sawọn ọmọ Naijiria ti wọn n ṣewọde tako aqwwọn ọlọpaa SARS atawọn ohun mi-in ti wọn lawọn ko fẹ mọ.

Ọrọ  ẹni to jọ wọn loju ju ni ti Alhaji Lai Mohammed, ẹni ti ṣe minisita feto iroyin toun naa ko sọ ohunkohun to jọ mọ ọn.

Ibeere tawọn eeyan n bira wọn bayii ni pe, njẹ o ṣee ṣe ki wọn ṣepade lai mẹnuba ọrọ ọhun rara ni, paapaa bo ṣe jẹ pe ko ju bii wakati meloo sira wọn ti wahala buruku ọhun bẹ silẹ l’Ekoo ti ipade wọn waye, tọrọ naa si tun n le si i lasiko ti ipade naa n lọ lọwọ niluu Abuja.

Leave a Reply