Awọn mọlẹbi bara jẹ gidigidi nibi isinku awọn sọja to ku ninu ijamba ẹronpileeni l’Abuja

Lọjọ Abamẹta, Satide, ni wọn ti sinku awọn oloogbe naa nilana isinku awọn ologun, pẹlu iyi ati ẹyẹ ti wọn maa n ṣe fun awọn akọni ti wọn ba ku soju ija.

Baaluu awọn ologun kan ni wọn fi gbe awọn oloogbe naa wa siluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa, lowurọ ọjọ Satide, wamuwamu si lawọn ṣọja duro bi wọn ti n fi mọto gbe awọn posi naa lati papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe lọ si mọṣalaaṣi apapọ ati ṣọọsi awọn ologun ofurufu (Nigerian Air Force Protestant Church) fun isin idagbere ati adura ikẹyin ni ilana ẹsin kaluku wọn. Lati ṣọọṣi naa ni wọn ti ko wọn lọ si itẹkuu awọn ologun to wa ninu ọgba wọn.

Ọpọ lara awọn mọlẹbi naa bara jẹ gidi, ọpẹlọpẹ awọn ologun ti wọn di awọn mi-in mu lara wọn, wọn fi imọlara ati ẹdun ọkan han bi kaluku wọn ṣe n sọrọ aro nipa ẹni wọn ti iku ja gba mọ wọn lọwọ lai ro ti. Ibanujẹ ati ẹkun rẹpẹtẹ lawọn mọlẹbi oloogbe kọọkan da bolẹ nigba ti wọn ke si wọn lati ṣẹyẹ ikẹyin, ki wọn fi eeru fun eeru, ki wọn si feepẹ fun eepẹ, lati ṣe o digbooṣe.

Nigba ti wọn ni kawọn mọlẹbi oloogbe kọọkan bọ siwaju ti wọn si n fun wọn ni asia ilẹ wa lati fihan pe ẹni wọn ja fun ilẹ wa doju iku ni, niṣe ni abilekọ kan digbo lulẹ pẹlu asia naa lọwọ rẹ, ni wọn ba sare gbe e digba-digba fun itọju.

Bakan naa ni obinrin mi-in tun daku lori aga to jokoo si lasiko ti Olori awọn oṣiṣẹ alaabo ilẹ wa, Major General Lucky E. O. Iraboh, n sọrọ lọwọ lorukọ Aarẹ Buhari.

Oriṣiiriṣii ọrọ ibanikẹdun lo ti n rọjo latigba ti iṣẹlẹ naa ti waye. Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari ṣapejuwe iku olori ogun atawọn jagunjagun yii bii igba ti ọta kan fun ilẹ wa ni ikuuku labẹnu, o ni ibi ti iṣẹlẹ naa bọ si lara ijọba oun buru jọjọ.

Leave a Reply