Awọn mọlẹbi Olufalayi tawọn kan lu pa l’Ado-Ekiti n beere fun idajọ ododo

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Inu ọfọ nla lawọn mọlẹbi ọkunrin ẹni ọdun marundinlaaadọta kan, Olufalayi Ọbadare, wa di asiko yii, ti wọn si n beere fun idajọ ododo lori bi awọn kan ṣe lu oloogbe naa pa lẹyin ti wọn ro pe ole ni.

Nibẹrẹ ọsẹ to kọja niṣẹlẹ naa waye lagbegbe Olujọda, niluu Ado-Ekiti.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ lawọn ọdọ adugbo kan to wa lagbegbe naa ni wọn ri ọkunrin kapẹnta ọhun to n rin lọ rin bọ bii ẹni to n wa nnkan, eyi lo si jẹ ki wọn fẹsun kan an pe o fẹẹ jale ni, ṣugbọn o sọ fun wọn pe oun gba iṣẹ kan si agbegbe tawọn eeyan ṣẹṣẹ n kọle si ọhun, oun ko si mọ ile naa gangan.

Nitori ero tawọn eeyan ọhun ni lọkan latari bi wọn ṣe ni awọn adigunjale kan ti n da agbegbe naa laamu tẹlẹ, wọn ko feti si nnkan ti ọkunrin naa n sọ ti wọn fi bẹrẹ si i na an, lẹyin ti wọn si la nnkan mọ ọn lori atawọn ẹya ara mi-in lo daku, ko too pada jẹ Ọlọrun nipe.

Nigba tiyawo oloogbe naa, Yẹmi, n sọrọ pẹlu ẹdun ọkan, o ni ọkọ oun kuro ni opopona Ado-Ekiti si Ilawẹ tawọn n gbe lọjọ naa pẹlu alaye pe oun ri iṣẹ kan, o si ya oun lẹnu pe awọn kan fẹsun ole kan an, ti wọn si pa a danu.

Bakan naa ni Abilekọ Ọmọwumi Idowu to jẹ mọlẹbi Olufalayi sọ pe nigba toun gbọ nipa iku oloogbe naa, oun ro pe o ṣaisan ni, nitori o ni iba diẹ lọjọ meloo kan si asiko naa, bẹẹ loun ba a sọrọ ṣaaju iṣẹlẹ ọhun, to si sọ foun nipa iṣẹ to fẹẹ lọọ ṣe.

Mọlẹbi oloogbe naa ti waa bẹ awọn agbofinro lati ṣiṣẹ takuntakun, ki wọn le mu awọn to ṣiṣẹ naa, ki wọn si fa wọn le ijọba lọwọ lati le jiya ẹṣẹ wọn.

Lasiko ta a pari akojọpọ iroyin yii, a gbọ pe eeyan bii meje lọwọ ti tẹ lori iṣẹlẹ naa, wọn si ti n sọ tẹnu wọn lọdọ awọn ọlọpaa.

Alukoro ọlọpaa Ekiti, ASP Sunday Abutu, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, bẹẹ lo ni loootọ lọwọ ti ba awọn kan, oku oloogbe si ti wa ni mọṣuari.

Leave a Reply