Mọlẹbi Oluwabamiṣe ti dẹrẹba BRT ji gbe beere fun idajọ ododo

Faith Adebọla

Mọlẹbi ọmọbinrin ẹni ọdun mejilelogun ti dẹrẹba mọto ijọba ipinlẹ Eko, BRT, ji gbe sa lọ, ti wọn si pada ri oku rẹ ni ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, Oluwabamiṣe Ayanwọla, ti n beere fun idajọ ododo lori iku ojiji ti wọn fi pa aburo oun.

Ẹgbọn ọmọbinrin to n ṣiṣẹ aṣọ riran naa, Elizabeth Ayanwọla, sọ lorukọ gbogbo mọlẹbi nigba ti akọroyin ALAROYE n fọrọ wa a lẹnu wo pe iku ọmọbinrin naa ko gbọdọ lọ lasan. O ṣalaye pe niṣe ni wọn fi iku ọmọbinrin ti ki i ṣe ijangbọn, to si ko gbogbo eeyan mọra naa da awọn lara.

O ni ki i ṣe Marwa ni ọmọ naa wọ, bẹẹ ni ki i ṣe bọọsi ero, nigba ti eeyan ko ba tun waa ni igbẹkẹle ninu mọto ijọba, ta ni eeyan fẹẹ gbẹkẹle bayii.

Elizabeth ni ti ki i baa ṣe pe oun ati ọrẹ rẹ jọ sọrọ, to si ṣe awọn atẹjiṣẹ kan lori foonu rẹ, ko sẹni ti yoo le sọ bi ọmobinrin naa ṣe rin irin rẹ, ọtọ ni ohun ti onikaluku iba si maa sọ.

O waa beere fun idajọ ododo lori iku to pa abigbẹyin ile wọn naa.

Leave a Reply