Awọn oṣere binu si b’ọlọpaa ṣe mu Mr Macaroni atawọn ẹgbẹ ẹ to fẹhonu han ni Lẹkki

Ọjọ keji, oṣu kẹta, ọdun yii, ni wọn sun igbẹjọ ti wọn fi kan ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa, Debọ Adedayọ, ti gbogbo eeyan mọ si Mr Macaroni atawọn ẹgbẹ ẹ ti wọn jọ mu si.

Ẹsun idaluru, apejọpọ to lodi ati ṣiṣe ohun to lodi si ofin Korona ni wọn fi kan wọn.

Adajọ ni wọn gbọdọ ṣeleri pe awọn ko ni i dalu ru mọ, ki wọn si huwa bii ọmọ daadaa bi wọn ba gba ominira.

Lẹyin ti agbẹjọro Mr Macaroni ti wọn pe orukọ rẹ ni Damilọla ṣe oniduuro fun un tan ni wọn ṣewe beeli rẹ, ṣugbọn awọn ọlọpaa ni awọn ko ni i fi awọn yooku silẹ, afi ti wọn ba mu oniduuro wa.

AKEDE AGBAYE yọ ọ gbọ pe aṣẹ ti wa pe wọn gbọdọ fi awọn eeyan naa silẹ lọjọ Abamẹta, Satide, naa lo mu ki gbajugbaja agba agbẹjọro nni, Mike Ozekhome, atawọn lọọya mi-in to wa nibẹ duro fun wọn.

 

Ohun to tun fa wahala lasiko ti wọn n yanju beeli wọn yii ni bi awọn yooku ti wọn jọ ko pẹlu Mr Macaroni ko ṣe ni fọto pelebe ti wọn yoo lẹ mọ iwe ti wọn fi gba beeli wọn, ni ori, bẹẹ ni wọn lo pọn dandan ki wọn too le jade kuro ni agọ ọlọpaa Panti naa.

Afigba ti wọn lọọ gbe onifọto kan wa lati waa ya awọn eeyan naa ni wọn too le fi wọn silẹ. Bẹẹ ni wọn fi dandan le e pe wọn gbọdọ lọọ ṣe ayẹwo arun Korona, ki wọn si mu esi rẹ lọwọ ti wọn ba n bọ nile-ẹjọ lọjọ keji, oṣu kẹta, ọdun yii.

Wẹrẹ bayii ni ọrọ ọhun bẹrẹ ni owurọ kutu ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, ti awọn agbofinro mu ọkan lara awọn gbajumọ oṣere tiata lorilẹ-ede yii, Ọgbẹni Debọ Adedayọ, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Mr Macaroni, atawọn kan ti wọn jọ n ṣewọde ni Too-geeti Lẹkki, l’Ekoo.

Loju-ẹsẹ ti iṣẹlẹ yii waye lawọn òṣèré ẹgbẹ ẹ ti n fẹhonu han, ta ko bi awọn agbofinro ṣe mu ọkunrin alawada yii atawọn mi-in ni Lẹkki.

Ọkan lara awọn oṣere tiata to kọkọ sọrọ, to si bu ẹnu atẹ lu ohun ti awọn agbofinro ṣe yii ni Kunle Afọdunrin, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Kunle Afod. Loju-ẹsẹ lọkunrin yii ti gba ori ikanni agbọrọkaye ẹ, Instagiraamu lọ, nibi to ti bu ẹnu atẹ lu iwa ti awọn agbofinro hu. Bẹẹ lawọn oṣere bii tiẹ paapaa naa ko ṣai fi aidunnu wọn han si iṣẹlẹ ọhun.

Kunle Afod sọ pe, “Ohun ti awọn ẹṣọ agbofinro ṣe ko bojumu rara, bẹẹ ni mi o fara mọ ọn rara, mo si mọ daju pe ọpọ awọn eeyan to ri iṣẹlẹ yẹn naa ni inu wọn ko dun si i. Ijọba yii ti sọ pe oun yoo kọ lu ẹnikẹni to ba jade lati waa fẹhonu han, ohun naa si ni wọn n ṣe bayii. Ohun ti mo fẹẹ beere lọwọ wọn ni pe ki lo de ti ijọba yii n ṣe ohun to le ko inira ba awọn eeyan orilẹ-ede yii?

“Ti ijọba yii ba mọ pe ohun ti oun n ṣe dara ni, ki lo de ti ko le jade lati ba awọn eeyan sọrọ, ṣugbọn to jẹ pe niṣe lo fẹẹ maa fi awọn ẹṣọ agbofinro ko awọn eeyan da satimọle. Kin ni Macaroni ṣe gan-an, ṣe ọbẹ ni wọn ba lọwọ ẹ ni abi wọn ba ibọn tabi ohun ija oloro kan. Ijọba yii n wa wahala, awa naa si ti ṣetan lati fun un daadaa. Kin ni ijọba yii fẹẹ para ẹ fun nitori ọrọ Too-geeti Lẹkki. Ṣaaju asiko yii ni Too-geeti ti wa kaakiri, ṣugbọn ti wọn pada pa wọn rẹ. Ọpọ eeyan ni wọn pa danu nibi Too-geeti yii, ti ijọba ko ri ohun kankan ṣe si i, ṣugbọn ti wọn fẹẹ ṣi i pada nitori owo ti wọn n pa nibẹ. Ṣe ẹ fẹẹ da ogun silẹ ni Naijiria ni, ṣugbọn mo fẹ ki ẹ ranti daadaaa pe ti ẹ ba da a silẹ, gbogbo wa naa la jọ maa wa ninu ẹ.”

Biọla Adekunle ninu ọrọ tiẹ sọ pe, “Ohun to ba eeyan ninu jẹ ni, ijọba yii ko ṣẹ daradara to. Bẹẹ ki i ṣe ijọba dẹmokiresi ti a beere fun niyi. Mr Macaroni ti wọn mu yii ki i ṣe janduku tabi ọdaran, ohun ti ijọba yii n ṣe ko le mu ilọsiwaju kankan ba wa, niṣe ni wọn tun n da wa pada sẹyin.”

 

Sheyi Ariyọ, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Shebaby ni tiẹ sọ pe, “Ohun to buru ni lati fi iru ẹ san Mr Macaroni to n pa awọn eeyan lẹrin-in, to n mu inu ọpọ eeyan dun lẹsan. Nigba wo lo di iwa ọdaran lati beere ẹtọ ẹ, tabi fẹhonu han lori ohun ti ko ba yẹ laarin ilu? Nibo gan-an ni ọkunrin yii ti kuna nitori to n beere fun ohun to yẹ ko ṣe gbogbo wa loore. Ohun ibanujẹ ni, bẹẹ ni inu mi ko dun rara.”

Ni ti Kunle Dasilva, ọkunrin oṣere tiata yii sọ pe, “Ọrọ emi ati Debo kọja pe a jọ n ṣere tiata, aburo mi daadaa ni, to si jẹ ̀ọmọluabi. Eyi to ṣẹlẹ yẹn ku diẹ kaato, ki Ọlọrun ṣaanu gbogbo wa.”

Ni ti Fẹmi Adebayọ, ori ikanni instagiraamu ẹ naa lo kọ ọ si bayii pe, “Ohun ibanujẹ ni bi wọn ti ṣe sọ iwa akikanju di bami-in mọ ẹ lọwọ. A jọ n ṣe e ni. Ma mikan rara.”

Yọmi Fabiyi ni tiẹ sọ pe, “Iwọde wọọrọwọ lati fẹhonu han wa lara ẹtọ ọmọniyan. Bẹẹ ni mi o ti i ri nnkan kan bayii to ṣe to jẹ mọ iwa ọdaran tabi ọna kan to gba to fi ko awọn eeyan jọ lati huwa to le di alaafia ilu lọwọ. Ẹsun ti wọn tori ẹ mu un paapaa ni ko ti i ye mi ti wọn fi sọ ọ sinu galagala bii ọdaran. Eyi ki i ṣe ohun to dara fun gbogbo awa ọdọ orilẹ-ede yii, bii ẹni tẹ wa mẹrẹ ni, bẹẹ ni wọn si n fi iru iwa yii ba wa loju jẹ lagbaaye. Ko si ibi naa ni agbaye ti wọn a ti gba awọn eeyan wọn niyanju lati lọ si iru orile ede ti wọn ti n tẹ ẹtọ eeyan loju mọlẹ bii eleyii.”

Ninu ọrọ Lateef Adedimeji lo ti sọ pe asiko niyi fun awọn ọlọpaa lati dawọ bi wọn ṣe n fi iya jẹ araalu duro. O ni lara ẹtọ ọmọniyan ni lati ṣewọde tabi fi ẹhonu han, paapaa nigba ti a ko si laye ijọba ologun.

Ọkan lara awọn oṣerebinrin to fi ilu America ṣebugbe bayii, Shẹrifat Oluwa, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Queen ninu ọrọ tiẹ sọ pe, “Oriṣiiriṣii fidio ni mo ti ri nibi ti wọn ti n ko awọn ọdọ Naijiria ju si atimọle nitori ti wọn fẹhonu han lori ohun ti wọn ko fẹ latọwọ ijọba. Niṣe ni omije n ja bọ loju mi poro, mo fẹẹ fi asiko yii ki Mr Macaroni ku iwa akọni, bẹẹ akikanju lo jẹ laarin awa ọdọ, aṣaaju ogun si ni paapaa ninu agbada.

Leave a Reply