Awọn oṣere fi atilẹyin han fun Tinubu lati di aarẹ ni 2023

Adefunkẹ Adebiyi

Ọkunrin ọmọ Ibo kan to maa n ṣe tiata lede oyinbo ati ede Ibo, John Okafor, tawọn eeyan mọ si Mr. Ibu, ti fi atilẹyin rẹ han fun Aṣiwaju ẹgbẹ APC, Bọla Tinubu, lati di aarẹ Naijiria ni 2023, bẹẹ lawọn oṣere mi-in labala yii naa ti ni Jagaban lawọn n ba lọ ni tawọn.

Ninu fidio kan ni Mr Ibu to maa n dẹrin-in pa awọn eeyan ninu fiimu ti n sọrọ nipa atilẹyin yii nibi ipade kan ti wọn pe akori ẹ ni ‘ South West Stands With Asiwaju Bola Tinubu’. Iyẹn ni pe ẹkun Guusu Iwọ-Oorun fara mọ Tinubu.

Ohun ti wọn sọ ni koko nibi ipade naa ni bi wọn yoo ṣe yan igbimọ ti wọn yoo gbe iṣẹ ipolongo yii le lọwọ.

Yatọ si Mr Ibu to wa nibẹ, ọkunrin Ibo kan toun naa jẹ oṣere tiata wa nibẹ pẹlu, orukọ rẹ ni Harry B. Anyanwu, ẹni ọdun mejilelọgọta (62) ni. Ohun toun naa sọ ni pe Bọla Tinubu lawọn fontẹ lu. Bẹẹ lawọn oṣere tiata mi-in naa wa nikalẹ ti wọn ni Aṣiwaju laayo awọn.

Fidio kan naa tun wa to ṣafihan awọn to wa nibi ipade yii, ti wọn n kọrin ki Tinubu pe oun lawọn n ba lọ.

Bọla Tinubu ko ti i kede pe oun fẹẹ dupo aarẹ ni 2023, ṣugbọn awọn ẹgbẹ to n polongo rẹ n pọ si i.

Leave a Reply