Awọn oṣere tiata ṣedaro ọkan ninu wọn to ku lọjọ keji ọjọọbi ẹ

 Faith Adebọla

 Ọkan-o-jọkan ọrọ ibanikẹdun lawọn oṣere atawọn ololufẹ tiata ṣi n kọ nipa gbajumọ oṣere tiata ilẹ wa kan, Abilekọ Ashabi Ayantunde, tawọn eeyan mọ si Iya Ifẹ, to jade laye lojiji.

Oru mọju ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu yii, lobinrin adumaadan naa mi eemi ikẹyin lẹyin aisan ranpẹ to ṣe e. Bẹẹ, ọjọ Aiku, Sannde, lawọn ololufẹ rẹ ṣi rọjo ikini ku oriire fun un fun ti ayẹyẹ ọjọọbi ẹ.

Aarẹ ọhun la gbọ pe o mu ki wọn sare gbe e lọ siluu Ile-Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun, nibi to ti n gba itọju labẹle, ibẹ lo si dakẹ si.

Ọkan lara awọn oṣere ẹlẹgbẹ ẹ, Bukky Smart, kọ ọrọ idaro nipa oloogbe yii sori atẹ ayelujara Instagiraamu ẹ, o ni “Ara mi ṣi n gbọn… Iya Ifẹ, sun-unre o, iya bii iya mi. Allah jọọ, dari awọn aṣiṣe ẹ ji i, ki O si tẹ ọkan ẹ si Paradise, aamin yaa Allah.

Onitiata mi-in, Ọlamilekan Ayinla, kọ ọ sori ikanni tiẹ naa pe: Mo ṣi n kọ ọrọ ikini kuu oriire ọjọọbi yin sori ikanni mi, lai mọ pe ẹ ti lọ, Iya Ifẹ. Ojoojumu ni mama yii maa n pe mi, ti wọn maa n ṣadura fun mi. Ṣe o pari niyẹn ni, Iya mi. Sun-unre o, Aṣabi.

Ọpọ eeyan lo tun sọrọ ibanikẹdun nipa oloogbe naa, awọn mi-in si darukọ akọle fiimu tobinrin naa ti fakọyọ bii ‘Ọrọ Aye’, ‘Atidade Kiniun’, ‘Afẹfẹ’, ‘Onibaara Aje’, ‘Old Ṣọja’ ati ‘Ogbologboo.’

Leave a Reply