Awọn agbofinro ti n mu awọn to ji nnkan ijọba atawọn ileeṣẹ aladaani l’Ọṣun

Idowu Akinrẹmi, Ikire

Ọwọ awọn oṣiṣẹ alaabo ti n tẹ awọn janduku ti wọn ji awọn nnkan ijọba ati ti ileeṣẹ alaadani kaakiri ipinlẹ naa.

Lati ọjọ Ẹti, Furaidee, lawọn janduku ti bẹrẹ si i lo asiko ifẹhonu han yii digunjale. Lara awọn ibi tawọn janduku ọhun ti ja, ti wọn si ko nnkan olowo iyebiye bii ounjẹ, dukia atawọn ohun eelo inu ile. Bakan naa ni wọn wọ ile Ọnọrebu Rasheed Olalekan Afolabi to wa niluu Ikirun, ti wọn si ko oriṣiiriṣii nnkan lọ nibẹ

Leave a Reply