Awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ṣewọde l’Oṣogbo, wọn ni ki Gomina Oyetọla san owo awọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lati agbegbe Old Garage, lawọn oṣiṣẹ-fẹyinti nipinlẹ Ọṣun ti gbera laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, wọn fi ẹsẹ rin gba ọna Ọja-Ọba lọ, ki wọn too mori le ọfiisi gomina ni Abere, ariwo ti wọn si n pa naa ni pe ebi-o-gaja-fọwọ-mẹkẹ lo le awọn sita.

Ọdun 2016 ni awọn agbalagba naa, ti wọn to igba (200) ni iye, sọ pe awọn fẹyinti lẹnu iṣẹ ijọba, ṣugbọn ti awọn ko ri owo mọda-mọda tijọba n yọ lori owo-oṣu awọn gba.

Nigba ti alaga wọn, Ọgbẹni Gbenga Ọyadare, n ba ALAROYE sọrọ, o ṣalaye pe ko si ootọ kankan ninu ariwo tijọba n pa kaakiri pe awọn n sanwo awọn oṣiṣẹ-fẹyinti l’Ọṣun nitori ki i ṣe gbogbo eeyan ni wọn n fun.

O ni aimọye lo ti ku laarin awọn latari airi owo tọju ara wọn, bẹẹ ni ọpọlọpọ ti di atọrọjẹ laduugbo nigba ti wọn ko ri ẹtọ wọn gba lọwọ ijọba. O ni awọn ọmọ wọn jade ileewe, ṣugbọn wọn ko riṣẹ ṣe.

Ọyadare fi kun ọrọ rẹ pe sisan miliọnu lọna ọọdunrun Naira ninu owo to to biliọnu lọna aadọta Naira ko yatọ si ẹni to n fi ori-ika kan omi sinu agbada gbigbona ti ina si wa labẹ rẹ.

O ni awọn ko ni i sinmi, bẹẹ lawọn ko ni i dakẹ, titi tijọba ipinlẹ Ọṣun yoo fi fun awọn ni ẹtọ awọn nitori oogun oju awọn ni.

 

Ọkan lara wọn, Ọparinde Sunday-Ọla, sọ pe oṣu kẹsan-an ọdun 2018, loun fẹyinti, ẹẹdimasita nileewe Baptist Primary School, Gbọngan, oun ko si ri tọrọ to n dan gba latigba naa.

O ni niṣe ni gbogbo nnkan nira foun, idi niyi ti gbogbo awọn fi n lọgun pe ki Gomina Oyetọla sanwo ifẹyinti awọn.

Nigba to n fesi si iwọde awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ọhun, Kọmiṣanna fun eto iroyin ati ilanilọyẹ awọn araalu, Funkẹ Ẹgbẹmọde, ṣalaye pe ohun to ṣẹlẹ naa jẹ ijọloju funjọba pupọ nitori ko ti i ju ọjọ mẹwaa lọ tipade waye laarin awọn adari awọn oṣiṣẹ-fẹyinti atijọba.

O lo ti to biliọnu lọna ogoji naira (#40b) tijọba ti san fun wọn laarin ọdun 2018 si asiko yii, bẹẹ ni awọn n yanju obitibiti gbese owo mọda-mọda ti awọn jogun.

Ẹgbẹmọde waa rọ awọn eeyan naa lati fiye denu, ki wọn ṣe suuru diẹ si i funjọba nitori Gomina Oyetọla ko fi ọrọ wọn ṣere rara.

Leave a Reply