Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Lẹyin ọjọ diẹ tijọba Gomina Dapọ Abiọdun bọ ninu iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ogun, awọn baba ati mama ti wọn ti fẹyinti lẹnu iṣẹ ọba nipinlẹ yii lo tun n ba gomina fa a bayii, wọn ni kijọba sanwo ajẹmọnu (Gratuity) awọn lẹyẹ-o-sọka.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii lawọn oṣiṣẹ-fẹyinti naa ṣewọde lagbegbe Abiọla way, l’Abẹokuta, pẹlu awọn akọle oriṣiiriṣii ti wọn gbe dani bii: Ẹ fagi le abadofin buruku tẹ ẹ ṣe lori owo ifẹyinti, Ọgbẹni gomina, dakun ma fẹto wa du wa lori owo ifẹyinti ati ti ajẹmọnu wa, ko si lọ-kabọ nibi sisan owo ifẹyinti awọn oloṣelu, sanwo wa, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Gẹgẹ bawọn eeyan yii ṣe wi, wọn ni owo ajẹmọnu awọn lati 2014 titi di asiko yii lawọn n beere, pẹlu tawọn to ṣiṣẹ nile ijoba ibilẹ, ti wọn si ti fẹyinti latọdun 2011 si asiko yii.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin iwọde naa, Alaga wọn nipinlẹ ogun, Ọgbẹni Waheed Oloyede, sọ pe awọn ko fara mọ ohun tijọba sọ nipa idaji miliọnu naira ti wọn lawọn yoo yọnda ẹ lati oṣu kin-in-ni, ọdun 2021, fun sisanwo ajẹmọnu yii.
Oloyede sọ pe ọdun mẹrinlelọgbọn (34 years) ni yoo gba ijọba lati san gbese biliọnu mejidinlaaadọrin (68billion) owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ogun to wa lọrun wọn pẹlu idaji miliọnu ti wọn ni awọn yoo fi bẹrẹ loṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yẹn. Eyi lo ni awọn ko ṣe fara mọ aba ijọba naa.