Awọn oṣiṣẹ ijọba Ekiti fẹẹ ba Fayẹmi k’ẹsẹ bọ ṣokoto ija o

Gbogbo ẹgbẹ awọn oṣịṣẹ patapata ti para pọ ni ipinlẹ Ekiti bayii o, wọn si ni awọn fun Gomina Kayọde Fayẹmi ni ọjọ mẹrinla pere, ti ko ba ṣe ohun ti awọn n fẹ, gbogbo awọn yoo da iṣẹ silẹ, oṣiṣẹ ijọba ẹyọ kan bayii ko si ni i ṣiṣẹ.

Ọjọ Abamẹta, Satide, oni yii naa ni wọn ha ipinnu wọn yii fawọn oniroyin ninu atẹjade ti wọn ju sita. Ado-Ekti ni wọn ti ṣepade wọn, wọn si fi ibinu han pe gbogob bi awọn ti kekeeke to pe iya n jẹ awọn oṣiṣẹ Ekiti, niṣe ni Fayẹmi kọ eti ọgbọn-in sawọn, afi bii ẹni pe ko gbọ ede ti awọn n sọ lẹnu ni. Wọn waa ni nibi ti ọrọ de bayii, ko sohun ti awọn le ṣe ju ki awọn jọ ki ẹsẹ bọ ṣokoto kan naa lọ.

Gbogbo awọn olori ẹgbẹ oṣiṣṣẹ mẹtẹẹta ipinlẹ naa, ti awọn NLC, TUC ati JNC pẹlu awọn akọwe wọn – Kọlapọ Ọlatunde, Ṣọla Adigun, Kayọde Fatomiluyi, Gbenga Olowoyọ, Kuloogun Lawrence ati Taiwo Akinyẹmi – ni wọn fọwọ si atẹjade ikilọ yii, ti wọn fi sọ pe gbogbo ẹni to ba mọ oju Fayẹmi ko ba awọn kilọ fun un.

Awọn oṣiṣẹ yii ni o ya awọn lẹnu kọja aala, iwa ọdalẹ gidi lawọn si ka a si, pe lati ọjọ tijọba Fayẹmi yii ti de, ti kinni naa si n lọ si bii ọdun meji bayii, Gomina naa ko mu ẹyọ kan bayii ṣe ninu gbogbo ibeere awọn oṣiṣẹ Ekiti, o kan n wo awọn bii pe Ọlọrun kọ lo ṣe ẹda awọn ni. Ṣugbọn, wọn ni, ọrọ naa ti doju ẹ bayii o, bi ọjo mẹrinla ba pe, ti Fayẹmi ko ba ti i wa nnkan kan ṣe, awọn yoo da iṣẹ rẹ lu u laya, awọn yo si jokoo sile awọn.

 

Leave a Reply