Awọn oṣiṣẹ ile-igbimọ aṣofin Ogun ti geeti pa, wọn bẹrẹ iyanṣẹlodi ailailọjọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni awọn oṣiṣẹ ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun darapọ mọ awọn ẹlẹgbẹ wọn kaakiri ipinlẹ, iyẹn ‘Parliamemtary Staff Association Of Nigeria’ (PASAN), wọn si bẹrẹ iyanṣẹlodi alailọjọ ti wọn fẹnuko le lori, wọn ti geeti abawọle igbimọ naa lai jẹ ki ẹnikẹni wọle.

Ohun ti wọn tori ẹ gbe igbesẹ yii ni pe wọn ni labẹ ofin orilẹ-ede yii, aaye gba ile-igbimọ lati da duro lori owo ti wọn ba nilo, ki i ṣe ijọba ni yoo maa la le wọn lọwọ, ti wọn yoo si maa fiya owo to tọ sile naa jẹ ẹ.

Alaga awọn PASAN nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni James Ọbanla, ṣalaye fawọn akọroyin lọjọ Iṣẹgun naa, l’Abẹokuta, pe ko si iṣẹ kan ti yoo jẹ ṣiṣe nileegbimọ yii titi digba ti aṣẹ ba wa pe kawọn da iyanṣẹlodi duro, bẹẹ ni Ogun ko da igbesẹ iyanṣẹlodi naa gbe, aṣẹ lati ọdọ ẹgbẹ naa lapapọ ni.

Ọbanla tẹsiwaju pe ọpọlọpọ igba lawọn ti kọwe sawọn ijọba ipinlẹ, pe ki wọn jẹ ki PASAN da duro nipa eto iṣuna rẹ, paapaa nigba ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọ lu u, ṣugbọn awọn ijọba ipinlẹ ko tẹle e.

Oṣu karun-un, ọdun 2020, ni Buhari ti buwọ lu aṣẹ yii gẹgẹ bo ṣe wi, o ni aṣẹ daadaa ti yoo pin agbara ti kaluku ni fun un ni, ti yoo si ṣagbẹkalẹ ohun to tọ si ẹka kọọkan.

Nigba to n ba awọn oṣiṣẹ to daṣẹ silẹ naa sọrọ, olori ile-igbimọ aṣofin Ogun, Ọnarebu Taiwo Ọlakunle Oluọmọ, ṣalaye pe awọn gomina ko lodi si pe kawọn oṣiṣẹ yii maa ṣeto owo wọn funra wọn. O ni awọn ohun ti wọn yoo fi mu aba ti Buhari buwọ lu naa ṣẹ lo ṣe koko lati ni ko too ṣee ṣe.

O ni eto ti n lọ lati bẹrẹ iṣẹ lori ohun ti PASAN n fẹ, nitori awọn abẹnugan ti ṣepade pẹlu awọn gomina, ireti si wa pe laarin ọsẹ meji si asiko yii, ọrọ to wa nilẹ yii yoo yanju.

Leave a Reply