Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ reluwee to n ge waya ọkọ oju irin bọ sọwọ ọlọpaa n’Ifọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Oṣiṣẹ ileeṣẹ reluwee lawọn ọkunrin mẹta yii, orukọ wọn ni Frank Obi, Eze Ogbonna ati James Ejor, ṣugbọn niṣe ni wọn tun n ji awọn waya kan nibẹ nitori apo ara wọn. Ọjọ kọkanla, oṣu kẹta yii, lọwọ palaba wọn segi ni Kajọla, Ifọ, nipinlẹ Ogun.

Ọlọdẹ to n ṣọ ileeṣẹ naa ti i ṣe Kwochason Global Gas Company, lo ri awọn marun-un kan ti wọn n ge waya to ni i ṣe pẹlu ọna reluwee ti wọn n ṣe lọwọ. Ṣugbọn nitori wọn pọ ju ọlọdẹ lọ, wọn ri waya naa ge, wọn si sa lọ.

Lẹyin ifisun ileeṣẹ yii ni teṣan ọlọpaa Ifọ, ni awọn ọlọpaa dọdẹ awọn eeyan naa de ibi ti wọn fara pamọ si, ọwọ wọn si ba awọn mẹta yii ti wọn jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ naa.

Ayùn ti wọn fi n ge irin ati waya ti wọn ge lọ naa lawọn ọlọpaa ri gba lọwọ wọn.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ pe ọga awọn, CP Edward Ajogun, ti paṣẹ pe awọn gbọdọ wa awọn meji to sa lọ naa ri, ki wọn le waa jẹjọ bii awọn yooku wọn tọwọ ba.

Leave a Reply