Awọn oṣiṣẹ ko daṣẹ silẹ mọ o

Aderounmu Kazeem

Lẹyin ipade bii wakati mẹfa laarin ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ NLC ati TUC pẹlu ijọba apapọ, wọn ti fagile iyanṣẹlodi to yẹ ko bẹrẹ loni-in.
Aago mẹjọ abọ alẹ ana ni ipade ọhun bẹrẹ laarin ikọ awọn oṣiṣẹ ati awọn aṣoju ijọba apapọ lẹyin ọpọlọpọ ijiroro, aago meji abọ oru ni wọn pari ipade, ti wọn si fẹnuko wi pe ki wọn dawọ ipe fun iyanṣẹlodi ọhun duro, nigba ti ijọba apapọ ti ṣeleri lati dawọ fifi owo kun ina mọnamọna duro fun ọsẹ meji.
Laarin ọsẹ meji yii ni ijọba apapọ sọ pe oun yoo ṣíṣẹ lori gbogbo igbesẹ ti oun ṣeleri wi pe oun yoo fi mu itura ba awọn eeyan orilẹ-ede yii.
Lara awọn minisita to ṣoju ijọba nibi ipade ọhun ni Timipre Silva, Dokita Chris Ngige, Festus Keyamo; Alhaji Lai Mohammed, ati Boss Mustapha tí i ṣe akọwe agba fun ijọba apapọ, bẹẹ làwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ wa nikalẹ pẹlu, ìyẹn Ayuba Wabba, Quadri Ọlalẹyẹ atawọn eeyan wọn.
Ohun ti wọn fẹnu ko si ni pe awọn yoo fagile iyanṣẹlodi ọhun fún ọsẹ méjì, nigba ti igbimọ ti ijọba fẹẹ gbé kalẹ yoo ṣe itọpínpín lori bi iye owo tawọn ileeṣẹ apinnaka ko ṣe wa ni idọgba pẹlu alakalẹ ajọ to n dari wọn, ìyẹn NERC. Bakan naa ni iwadii yoo waye idi ti ileeṣẹ apinaka ko fi ti i ko mita igbalode bii miliọnu mẹfa jade fun lilo araalu.
Eyi atawọn nnkan mi in ni wọn sọ pe wọn yoo lọọ wo fun ọsẹ meji, ki iyanṣẹlodi too le tẹ siwaju.
Laarin ọsẹ meji yẹn, wọn ti sọ pe awọn ileeṣẹ apinnaka kankan ko gbọdọ fowo kun owo ina titi digba tí abajade iwadii ti wọn lọọ ṣe yii yoo ṣe jáde.
Ni ti epo pẹtiroolu, ìjọba apapọ ti sọ pe igbesẹ yoo bẹrẹ lori bi awọn ileeṣẹ ifọpo wa yoo ṣe maa ṣíṣẹ pada, eyi ti yoo dẹkun bi a ṣe n lọọ fọ epo wa nilẹ okeere eyi to mu ijọba maa fowo iranwọ kun un, to si n da ọpọ wahala silẹ.
Ìjọba ti ni ileeṣẹ ifọpo to wa ni Kaduna, Port Harcourt àti Warri loun yoo mojuto bayii, bakan naa lanfaani yoo tun wa lati da awọn ileeṣẹ ifọpo alabọọde silẹ, ki opin le ba lílọ soke okun lọọ maa fọ epo, eyi to n sọ ọ dọwọn.
Ohun mi-in ti ijọba tun ṣeleri ẹ ni igbesẹ lori ipese awọn ohun amayedẹrun fun araalu bii ipese owo iranwọ fawọn agbẹ, eto owo iranwọ fun awọn oṣiṣẹ ijọba, eto iranwọ lori ile olowo pọọku, bọọsi akero ti yoo maa lo afẹfẹ idana atawọn eto iranwọ mi-in ki aye le rọrun fun araalu

Leave a Reply