Awọn oṣiṣẹ Ọṣun kọ lẹta si Oyetọla, wọn ni ko san ajẹẹlẹ owo-oṣu awọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọṣun, State of Osun Joint Labour Movement, ti kọ lẹta si Gomina Adegboyega Oyetọla lati beere fun ajẹẹlẹ owo-oṣu ati owo ifẹyinti wọn.

Lẹta naa, eleyii to tẹ Alaroye lọwọ, ni wọn kọ lọjọ keje, oṣu keji, ọdun yii, ti Alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ l’Ọṣun, Jacob Adekomi, alaga JNC, Bayọ Adejumọ, alaga TUC, Adekọla Adebọwale si fọwọ si i.

 

Lara ohun ti wọn n beere fun ni sisan owo alajẹṣẹku oṣu mẹrin tijọba yọ ninu owo-oṣu awọn oṣiṣẹ kan loṣu kẹfa, ọdun 2019, ati laarin oṣu kẹrin si oṣu kẹfa, ọdun 2020.

Bakan naa ni wọn n beere fun afikun owo to tọ si awọn oṣiṣẹ ti wọn gba igbega bẹrẹ lati ọjọ kin-in-ni, oṣu kọkanla, ọdun 2021, kijọba si fọwọ si igbega fun wọn, ki anfaani si tun wa fun awọn to ba fẹẹ lọ lati ẹka kan si ekeji.

Wọn ṣalaye pe gbogbo ibeere yii lo ti wa ninu iwe adehun tijọba ṣe pẹlu awọn, ṣugbọn ijọba ko ti i mu adehun wọn ṣẹ.

Gbigbe igbesẹ lori awọn ibeere yii ni kiakia, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ sọ pe ohun ni yoo mu ki iṣọkan ati ifẹ tubọ maa jọba laarin awọn ati ijọba.

Leave a Reply