Awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ogun bẹrẹ iyanṣẹlodi, won lawọn ko ni i ṣiṣẹ rara

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Aago mejila oru oni, ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹsan-an yii, ni awọn oṣiṣẹ kaakiri ipinlẹ Ogun yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọsẹ kan ti wọn ti kilọ ẹ funjọba tẹlẹ pe awọn yoo ṣe bijọba Gomina Dapọ Abiọdun ba kọ lati san ẹgbẹrun Naira lọna ọgbọn, gẹgẹ bii owo oṣu to kere julọ.

Alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nipinlẹ yii, Kọmureedi Emmanuel Bankọle, lo sọ eyi di mimọ l’Abẹokuta lanaa ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lẹyin ipade oniwakati mẹta ti ẹgbẹ NLC to n ṣoju oṣiṣẹ atawọn aṣoju ìjọba jọ ṣe.

Bankọle sọ pe ipade awọn naa foriṣanpọn ni, nitori ijọba ṣaa n sọ pe kawọn oṣiṣẹ ṣi ni suuru ni, awọn yoo bẹrẹ si i sanwo ọhun to ba ya.

Alaga NLC nipinlẹ Ogun naa tẹsiwaju pe awọn òṣiṣẹ ko le ṣe suuru kankan mọ, nitori ipinlẹ Ogun ko toṣi debii pe ijọba ko ni i le sanwo tijọba apapọ ti faṣẹ si tipẹ naa. O ni ijọba yii wulẹ n fiya jẹ awọn oṣiṣẹ pelu bi wọn ṣe kọ ti wọn ko sanwo naa ni.

Ṣaaju ni ẹgbẹ to n gbeja àwọn òṣìṣẹ́ yii ti fun ijọba ni gbedeke ọjọ mẹrina pe ki wọn fi bẹrẹ si i sanwo oṣu ẹlẹgbẹrun lọna ọgbọ́n to kere julọ yii, ti wọn ni awọn yoo bẹrẹ iyansẹlodi bi wọn ko ba bẹ̀rẹ̀ si i sanwó naa ti ọjọ mẹrinla ba  fi pe. Gbedeke naa lo pari lọjọ Iṣẹgun ana yii, ti wọn fi gúnlè iyansẹlodi onikilọ ti yoo gba ọsẹ kan  gbako yii.

Ninu awọn ẹtọ ti ẹgbẹ NLC ati TUC to jẹ akẹgbẹ wọn n beere ni pe kijọba ipinlẹ Ogun fagile àbádòfin to n ṣatunṣe si owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ, wọn ni ki wọn sanwo ajẹmọnu (Gratuity) awọn oṣiṣẹ bi wọn ṣe n fẹyinti, wọn ni kijọba sanwo liifu ọdun mẹfa tawọn èèyàn ti lọ ti wọn o ri gba, owo agbega ọdun kẹta ati owo ifẹyinti oṣu mẹtalelaadoje kan to wa lọrun ijọba naa, wa ninu ẹtọ tawọn olori oṣiṣẹ n beere fawọn eeyan wọn.

Bijọba ba dahun sawọn nnkan wọnyi ni yoo sọ ogun ti yoo ṣẹlẹ lẹ́yìn iyanṣẹlodi onikilọ yii.

Ṣugbọn oludamọran pataki fun Gomina Dapọ Abiọdun lori ọrọ awujọ, Remmy Hazzan, to sọrọ lori iyansẹlodi yii sọ pe ohun ijọloju lo jẹ pe ẹgbẹ òṣìṣẹ le gunle iyanṣẹlodi, nitori eyi tako ohun tawọn jọ sọ ninu ipade tawọn ba awọn egbẹ naa ṣe.

O ni loootọ ni pe ohun tawọn oṣiṣẹ n beere fun tọna labẹ ofin, sugbọn ipo ti apo ijọba ipinlẹ Ogun wa bayii ni ko ti i jẹ ko ṣee ṣe funjọba lati ṣe ohun tawọn eeyan yii n beere.

Hazzan waa ni ijọba yoo maa bawọn jiroro lori ọrọ yii ṣa titi ti yoo fi yanju, ko ma di pe wahala yoo ba eto ọrọ-aje ipinlẹ yii.

Leave a Reply