Awọn oṣiṣẹ UNIOSUN gba kootu lọ, wọn ni afi ki EFCC yẹ iṣẹ ọga-agba ibẹ wo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn oṣiṣẹ Osun State University ti lọ si ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa niluu Oṣogbo, lati gba aṣẹ ti yoo pọn ọn ni dandan fun ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra lorileede yii, EFCC, lati ṣewadii awọn iwa aṣemaṣe ti ọga agba ileewe naa, Ọjọgbọn Labọ Popoọla n hu.

Awọn oṣiṣẹ ọhun, labẹ Non-Academic Staff Union of Educational and Associated Institution (NASU), sọ pe owo to to miliọnu lọna ọgọrun-un naira, eleyii to jẹ ti ileewe naa, ni Popoola ti ṣe baṣubaṣu.

Nigba ti igbẹjọ naa, eleyii to ni nọmba FHC/OS/CS/44/2020 waye ni kootu ọhun lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, agbẹjọro fun awọn olupẹjọ, Kanmi Ajibọla, sọ pe ibeere awọn olupẹjọ wa nibamu pẹlu alakalẹ ofin orileede wa.

Ajibọla ṣalaye pe olujẹjọ ti mọ nipa igbẹjọ naa, o si rọ ile-ẹjọ lati gbọ ẹjọ ọhun kiakia, ki wọn si paṣẹ fun EFCC lati bẹrẹ iwadii lori owo ileewe naa ti wọn fẹsun kan Popoọla pe o na ninakunaa.

Awọn oṣiṣẹ naa sọ nile-ẹkọ pe lati ọdun 2018 ni awọn ti kọ oniruuru iwe ẹsun to lagbara si EFCC nipa Ọjọgbọn Popoọla, ṣugbọn ti wọn ko gbe igbesẹ kankan.

Ṣugbọn ninu ọrọ agbẹjọro fun EFCC, M. S. Usman ati agbẹjọro fun ọga-agba nileewe naa, S. B. Ayẹni rọ kootu lati fun wọn lanfaani diẹ, ki wọn le raaye ṣagbeyẹwo iwe ipẹjọ ti awọn ṣẹṣẹ gba laipẹ yii.

Agbẹjọro Kanmi Ajibọla sọ ni tiẹ pe ṣe lawọn agbẹjọro EFCC ati ti Popoọla mọ-ọn-mọ fẹẹ di igbẹjọ lọwọ tori wọn ti ri iwe ipejọ naa lasiko ti wọn ni lati fesi le e lori.

O fi kun un pe ti ile-ẹjọ ba ti le gba lati fun wọn lasiko diẹ, wọn gbọdọ san faini ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un (#100,000) gẹgẹ bii owo gba-ma-binu fun awọn olupẹjọ.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Peter Lifu ṣalaye pe ki olujẹjọ kọọkan san ẹgbẹrun lọna ogun naira fun olupẹjọ latari asiko wọn ti wọn fi ṣofo.

Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kọkanla ọdun yii.

Leave a Reply