Awọn ọba Akoko gba ijọba nimọran lori eto aabo to mẹhẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ọba alade kan l’Akoko ti pa ẹnu pọ lati gba ijọba apapọ nimọran lori wahala eto aabo tawọn eeyan orilẹ-ede yii n koju lọwọ.

Akala tilu Ikaram, nijọba ibilẹ Ariwa Ila Oorun Akoko, Ọba Andrew Mọmọdu, ni iwa ọdaran to n fi igba gbogbo waye kaakiri orilẹ-ede yii ati bi wọn ṣe n ransẹ pe awọn ọmọ ologun lati waa mojuto eto aabo nibikan ti fidi rẹ mulẹ pe apa awọn ọlọpaa nikan ko fẹẹ ka didawọ iwa ọdaran duro mọ lasiko yii.

Akaram ni ọna kan soso tijọba fi le din iwa ọdaran ku lawujọ ni ki wọn gba ọpọlọpọ awọn akọsẹmọsẹ ọlọpaa kun awọn to ti wa nilẹ.

O ni ijọba gbọdọ ra awọn nnkan ija igbalode fawọn ọlọpaa ki iṣẹ aabo ti wọn n ṣe baa le rọrun si i.

Ọba Mọmọdu tun rọ ijọba apapọ ati ti ipinlẹ lati faaye gba dida ileesẹ ọlọpaa ẹsẹkuku silẹ, nitori ojuṣe ijọba to kunju oṣunwọn ni lati peṣe aabo to peye fawọn araalu.

Olubaka ti Ọka Akoko, Ọba Yusuf Adebori, ninu ọrọ tiẹ gba awọn araalu nimọran lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba.

O ni wọn ko gbọdọ da gbigbogun ti iwa ọdaran da ijọba nìkan nitori pe ojuṣe gbogbo araalu ni lati ri i pe eto aabo fẹsẹ mulẹ lagbegbe wọn.

Kabiyesi tun rọ awọn eeyan lati pa gbogbo ofin ati ilana tijọba fi lelẹ lori itankalẹ arun Korona mọ lasiko ayẹyẹ ọdun to n lọ lọwọ.

Adele Ọba ti Akunnu Akoko, Ọmọọba Tọlani Orogun, ni awọn eeyan ilu Akunnu, Ikakumọ, Auga, Isẹ, Ibọrọpa Ugbe (Isowọpọ) nijọba ibilẹ Ariwa Ila Oorun Akoko, ko ni i gbagbe ohun toju wọn ri lọwọ awọn ajinigbe atawọn Fulani darandaran lọdun 2020 to n pari lọ yii.

Yatọ si awọn ire oko wọn ti awọn Fulani bajẹ, ọpọ awọn agbẹ lo ni wọn ti fidi mọle ti wọn ko lọ soko mọ nitori ibẹru awọn darandaran.

Kabiyesi ni ni agbegbe ti wọn n pe ni Isowọpọ yii lo yẹ kijọba mojuto daadaa, nitori pe awọn ni wọn wa lẹnu ibode ipinlẹ Ondo, Edo ati Kogi.

Ọga ọlọpaa to n mojuto agbegbe Ikarẹ Akoko, Ọgbẹni Razak Rauf, bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ awọn eeyan agbegbe naa.

O ni ohun to lewu ni ki awọn araalu da ọrọ eto aabo da awọn ọlọpaa tabi ijọba nìkan.

Ọga ọlọpaa ọhun ni awọn eeyan Akoko gan-an le jẹrii si i pe awọn n sagbara lori ọrọ gbigbogun ti iwa ọdaran lagbegbe naa.

Leave a Reply