Awọn ọba alaye tuntun gbọpa aṣẹ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ko din lawọn ọba tuntun marun-un ti wọn ṣẹṣẹ gbọpa aṣẹ lati ọwọ Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, lọsẹ to pari yii.

Lara awọn ọba alade ti gomina ṣẹṣẹ fun lọpa aṣẹ naa ni Ìrẹ̀sì tilu Osí, Ọba David Ọlajide, ati Ojogbabrika ti Ilado, Ọba Johnson Kayọde Ajọmale, eyi to wa n’ijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ.

Awọn yooku ni Ọba Olowoniyi Adeniyi Abẹjoye, Olúrọ̀kún ti Ìrọ̀kún, Ọ̀rúnmìjà tìlú Idigbẹngbẹn, Ọba Ọlatuja Anthony Anjọrin, ati Ọba Kalẹjaye Rotimi Williams ti i ṣe Monẹhin ti Obinẹhin, nijọba ibilẹ Ilajẹ.

Igbesẹ yii waye latari atunto ti ijọba ṣe sọrọ oye jijẹ laipẹ yii, eyi to fun awọn ọba alaye ati olori agbegbe kan lanfaani lati gba igbega kuro nipo ati aaye ti wọn wa tẹlẹ lọ si ipele miiran.

Awọn ọba tuntun naa jẹ isọri kin-in-ni ti yoo gba ọpa aṣẹ gẹgẹ bii ọba ninu awọn Olu ati Baalẹ mejilelọgọta ti ijọba kede agbega wọn laipẹ yii.

Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Orumisan Ayedatiwa, lo ṣoju ọga rẹ níbi ayẹyẹ gbigba ọpa aṣẹ awọn ọba tuntun ọba tuntun mẹtẹẹta to ṣẹṣẹ gbọpa aṣẹ lati ijọba ibilẹ Ilajẹ ọhun.

Ayedatiwa rọ awọn ọba naa lati ri ipo tuntun tí wọn wa gẹgẹ bii anfaani lati sin awọn eeyan wọn, ki wọn si rí i daju pe alaafia ati ifọkanbalẹ jọba lagbegbe ti wọn jọba si.

Kọmisanna fun ọrọ oye ati ijọba ibilẹ nipinlẹ Ondo, Akọgun Akinwunmi Ṣoworẹ, ni aṣoju gomina nibi eto gbigba ọpa aṣẹ Irẹsi tilu Osi ati Ojogbabrika ti Ilado. O fi asiko naa dupẹ lọwọ Akeredolu fun ifaraji rẹ lati yanju wahala ọlọjọ pipẹ to saaba maa n waye lori ọrọ ọba jíjẹ nipinlẹ Ondo. Bakan naa lo parọwa fun awọn to jẹ anfaani ọhun lati fi ṣiṣẹ takuntakun fun idagbasoke agbegbe wọn.

 

Ni nnkan bii osu diẹ sẹyin ni Gomina Akeredolu ṣe agbekalẹ igbimọ kan, eyi to pe ni Igbimọ Onidaajọ Chris Ajama. Arakunrin ni oun gbe igbimọ ọhun kalẹ lati le ṣe atunṣe ati atunto si ohunkohun to jẹ mọ ọrọ oye ni gbogbo ilu ati ileto to wa kaakiri ipinlẹ Ondo.

Aketi ni abajade igbimọ ọhun ni yoo yanju, tí yoo si tun fopin si gbogbo wahala ati rogbodiyan to n lọ lọwọ lori ọrọ oye jijẹ lawọn ilu kan nipinlẹ Ondo, ati eyi to le tun fẹẹ suyọ lọjọ iwaju.

Inu oṣu Kẹsan-an, ọdun yii ni Akeredolu kede igbega ọgọọrọ awọn ọba alaye kan ni ibamu pẹlu abajade iwadii igbimọ naa.

Awọn ọba alaye kan ni wọn gba igbega lati onipo keji ti wọn wa tẹlẹ si onipo kin-in-ni, wọn gbe awọn ori-ade kan ga lati ipo kẹta si onipo keji, nigba ti awọn Baálẹ̀, Olu ati Ọlọja bíi mejilelọgọta gba igbega si ọba onipo kẹta.

Leave a Reply