Awọn obi ati olukọ ta ko bijọba ṣe kọ lati ṣi ileewe ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Nitori bijọba ṣe kọ lati ṣi awọn ileewe pada nipinlẹ Kwara, awọn obi ati olukọ ileewe aladaani ni igbesẹ naa ko bojumu rara.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, lawọn eeyan ọhun fẹhonu niluu Ilọrin. Wọn ni ebi ti fẹẹ lu awọn pa bawọn ṣe n jokoo sile, nitori idi eyi, kijọba ṣaanu awọn, ki wọn ṣi awọn ileewe ni kiakia.

Alaga ẹgbẹ awọn oludasilẹ ileewe aladaani ni Kwara, National Association of Proprietors of Private Schools, Dokita Rahaman Adetunji, ṣalaye pe jijokoo sile lai ṣe nnkan kan ti su awọn akẹkọọ atawọn olukọ.

O ni pẹlu bi ijọba ṣe ṣi ileewe fun idanwo aṣekagba, WASCE, o fi han pe awọn ileewe ti ṣee ṣi, nitori pe ko si akẹkọọ kankan to jokoo ṣedanwo to lugbadi arun Korona laarin asiko ti idanwo naa fi waye.

Adetunji ni, “Awọn ileejọsin, ọja atawọn mi-in to jẹ pe o rọrun lati ko arun Korona nitori ero rẹpẹtẹ to maa n wa nibẹ gan-an ti di ṣiṣi, ki waa lo fa a ti ileewe ṣe maa wa ni titi.”

O ni o kere tan, bii ida marundinlọgọrun-un awọn ileewe aladaani to wa ni Kwara lo ti ṣeto ilana ti wọn yoo fi daabo bo awọn akẹkọọ ati olukọ lọwọ lilugbadi arun naa.

O rọ ijọba Kwara lati gbe igbesẹ kia, ko si kede asiko ati ilana iwọle awọn akẹkọọ

Leave a Reply