Awọn obi Dada ti wọn pa l’Oke-Igbo bẹbẹ fun idajọ ododo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn obi ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ti wọn pa sinu igbo kan niluu Oke-Igbo loṣu to kọja ti ni idajọ ododo lawọn n fẹ lori awọn to ṣeku pa ọmọ wọn.

Gẹgẹ bi alaye ti Abilekọ Bọsẹde Ọmọniyi to jẹ iya oloogbe, Dada Pius Ọmọniyi, ṣe f’ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii, o ni ile loun wa ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ kẹrinla, oṣu to kọja, nigba ti ẹnikan to porukọ rẹ ni Abbey Ojo waa tan ọmọ oun jade kuro nile wọn to wa lagbegbe Okesa, Oke-Igbo.

O ni oun tun pade Dada ati ọrẹ rẹ yii nibi ti wọn ti n ṣere lasiko ti oun kiri ẹja lọ saarin ọja lalẹ ọjọ kan naa lai mọ pe ko ni i pada wale mọ.

Lẹyin ti ko ri i ko wale waa sun lọjọ keji lo too ṣẹṣẹ pariwo ọrọ naa sita, tawọn eeyan si tọpasẹ Abbey to waa pe e nile lọ sile awọn obi rẹ.

Wọn fi iṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa Oke-Igbo leti, nibẹ ni wọn si ti sọ fun wọn pe awọn ri oku ẹnikan lọna abule Awọ, ni nnkan bii ọjọ mẹta sẹyin.

Wọn gba wọn nimọran ati lọọ wo oku ọhun ni mọṣuari ileewosan ijọba to wa l’Ondo.

Abilekọ Bọsẹde ni awọn ba oku ọmọ awọn ni mọsuari naa loootọ ti wọn ti ge ori, apa ati ẹsẹ rẹ mejeeji lọ.

O ni Abbey pada jẹwọ ni tesan pe oloogbe ọhun ati ẹnikan ti wọn n pe ni Tobi Amọdu ni wọn jọ lọ soko lọjọ ti awọn jọ jade.

Loju ẹsẹ lawọn ọlọpaa ti fi panpẹ ofin gbe Tobi, ti wọn si fi oun ati Abbey ṣọwọ si olu ileesẹ wọn to wa l’Akurẹ fun ẹkunrẹrẹ iwadii.

Awọn afurasi mejeeji yii la gbọ pe wọn jẹwọ fawọn ọlọpaa lasiko ti wọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo pe iṣẹ Babalawo lawọn n kọ lọwọ.

Alagba Pius Ọmọniyi to jẹ baba oloogbe ni o to bii ọsẹ kan lẹyin tisẹlẹ yii waye ki oun too gbọ nipa rẹ.

O ni iṣẹ awọn to n tun bata ṣe ni Dada kọ, ati pe nigba to ku ọjọ mẹfa pere ko di ọga ara rẹ ni wọn pa a nipakupa.

O ni ibi toun atawọn ọlọpaa jọ fi ọrọ si ni pe ki awọn mejeeji tọwọ tẹ ṣi wa lọdọ wọn titi ti wọn yoo fi ri awọn afurasi mẹta ti wọn lawọn n wa mu.

Alagba Pius ni kayefi lo ṣi n jẹ foun bi wọn ṣe pada yọnda Abbey ati ekeji rẹ ni kete ti oun pada sẹnu iṣẹ lẹyin ọjọ mẹrin pere ti wọn ti wa latimọle, ti wọn si tun n gba oun nimọran lati tete gbe igbesẹ lori ati gbe oku ọmọ oun kuro ni mọsuari ki oun si lọọ sin in.

O ni awawi awọn ọlọpaa ni pe o ṣee ṣe ki awọn ti wọn mu ọhun ma mọ ohunkohun nipa ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Ọsẹ to kọja yii to ni awọn pada lọ ni ri Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, pasẹ ki wọn tun lọọ mu awọn ọmọkunrin naa, ki wọn si da wọn pada si atimọle lẹyẹ-o-ṣọka, bo tilẹ jẹ pe awọn mejeeji ṣi wa nigboro tí wọn n rin kiri bo ṣe wu wọn titi di ba a ṣe n sọrọ yii.

Bakan naa lo tun fi aidunnu rẹ han si bi Olu Oke tiluu Oke-Igbo, Ọba Lawrence Babajide, ṣe kuna lati gbe igbesẹ lori ọrọ naa lẹyin ti wọn ti ṣalaye ohun gbogbo to ṣẹlẹ ni aafin.

Alagba Ọmọniyi ni ọmọ oun lẹni kẹta ti awọn onisẹẹbi wọnyi ṣeku pa, ti wọn si yọ ẹya ara wọn lọ laarin oṣu mẹta pere niluu Oke-Igbo.

Idi ree to fi n rọ ijọba ati ọga ọlọpaa patapata lorilẹ-ede yii lati dìde si ọrọ naa, ki iku ọmọ rẹ ma baa ja si asan.

Leave a Reply