Awọn obi pe ọmọ wọn atiyawo ẹ lẹjọ, tori wọn o rọmọ bi lẹyin ọdun mẹfa igbeyawo wọn

Bo ba jẹ ori tẹlifiṣan lọrọ ọhun ti ṣẹlẹ, awada kẹrikẹri leeyan iba ro pe wọn n ṣe, ṣugbọn eegun to ba ti jade ti kuro ni aiwo o, ara meriyiri ni bawọn obi kan, Sanjeev Prasad, atiyawo ẹ, Sadhana, ṣe pe ọmọ wọn, Shrey Saga, ati iyawo rẹ, lẹjọ si kootu, wọn lawọn o le ni suuru mọ lẹyin ọdun mẹfa igbeyawo wọn, awọn fẹẹ ri ọmọọmọ awọn, ti wọn o ba si le fawọn ni ọmọọmọ, ki wọn san owo itanran rẹpẹtẹ tori airọmọbi.
Iṣẹlẹ to yaayan lẹnu yii waye ni ipinlẹ Ariwa orileede India kan ti wọn pe ni Uttarakhand, ẹsun ti wọn fi kan tọkọ-taya to n woju Ọlọrun naa ni pe wọn ti n jẹ kawọn ni idaamu ọkan, tori agbọkanle awọn lori igbeyawo wọn pe ẹyin iyawo ko ni i mọ ẹni ti n pada ja sofo, ọmọọmọ tawọn fẹẹ maa ri gbe jo, tawọn reti la maa ba ṣere lasiko ifẹyinti lẹnu iṣẹ ọba ni wọn taku ti wọn o pese fawọn yii, lẹyin ọdun mẹfa tawọn ti ṣegbeyawo alarinrin fun wọn.
Bo tilẹ jẹ pe ọkọọyawo naa ati iyawo rẹ ko ti i fesi lori ẹsun ti wọn fi kan wọn yii, boya wọn jẹbi tabi wọn ko jẹbi, ṣugbọn wọn wa ni kootu nigba tawọn obi wọn n ṣalaye idi tawọn fi pe wọn lẹjọ lọsẹ to kọja yii.
Sanjeev, iyẹn baba ọkọ, to rojọ ni kootu sọ pe gbogbo owo toun ati iyawo oun ti tọju pamọ lawọn na le ọmọ awọn lori lati tọ ọ dagba tori ẹyọ kan pero naa lawọn bi, awọn si ti foju sọna pe eyi to ku tawọn ko ri bi, ọmọ kan ṣoṣo t’Ọlọrun fi tawọn lọrẹ yii lo maa bi i fawọn. O ni ẹgbẹrun marundinlaaadọrin owo dọla ($65,000) lawọn fi ran ọmọ naa niwee lorileede Amẹrika, ko lọọ kẹkọọ awakọ ofurufu ti wọn n pe ni pailọọti.
Nigba to de pada si India lọdun 2007 ti ko riṣẹ ṣe, awọn obi yii naa lo n gbọ bukaata ẹ niṣo fun bii ọdun meji, titi to fi papa ri iṣẹ awakọ ofurufu kan gba, to si n gbowo gidi.
O loun ati mama ẹ lawọn ṣeto bo ṣe ri iyawo arẹwa kan fẹ, ọdun 2016 lawọn si ṣegbeyawo alarinrin foun ati Shubhangi Sinha, iyawo ọṣingin ti wọn fẹ fun un. Ireti awọn nigba naa ni pe obinrin naa maa bi isun, o maa bi iwalẹ, awọn si maa maa ri ọmọọmọ awọn ba ṣere laipẹ.
Afi bi ọdun kan ṣe kọja, tikeji kọja, ikẹta kọja, titi to fi di ọdun mẹfa bayii, ti wọn o gbọ po, wọn lobinrin yii ko loyun owurọ dalẹ ri, gbogbo aajo to si yẹ kawọn ṣe lawọn ṣe, eyi tawọn ko mọ ni boya ọmọ awọn ni ko le faya iyawo ẹ daadaa ni o, boya iyawo si ni ile ọlẹ rẹ ti pajude ni, tori awọn o ba wọn denu yara loru ti tọkọ-taya wọn ba n sun oorun ọmọ.
Ṣa, awọn obi yii rọ ile-ẹjọ pe ki wọn bawọn faṣẹ si i, pe laarin ọdun kan sasiko yii, to ba jẹ bakan naa ṣi lọmọ ṣe ori lọdọ awọn eeyan yii, ti wọn o ba fi rọmọ bi, ki wọn sanwo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un mẹfa aabọ owo dọla ($650,000) fawọn, tori ijakulẹ nla ati idaamu ọkan ni airọmọbi wọn ti fa foun ati iyawo oun tawọn jẹ obi ọkọ.
Wọn ti sun igbẹjọ naa siwaju, gẹgẹ bi ikanni news.sky ṣe sọ lori ayelura.

Leave a Reply