Awọn obi Yinka Odumakin bara jẹ gidigidi nigba ti wọn tufọ iku rẹ fun wọn

Lati ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹta, oṣu kẹrin, ọdun yii, ti wọn ti kede iku agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹrẹ nni, Yinka Odumakin, lo ti nira fun awọn mọlẹbi ọkunrin naa lati tufọ iku rẹ fun awọn obi ẹ.

Abẹwo ALAROYE si ile wọn to wa ni Orita-Moro, nijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun, lọjọ Satide naa fi han pe baba ati iya Odumakin ko gbọ nnkan kan nipa iku ọmọ wọn, koda, gbogbo awọn ọlọja ti wọn ni ṣọọbu niwaju ile naa ni wọn n taja wọn lọ pẹrẹu.

A gbọ pe awọn mọlẹbi ti wọn wa layiika ni wọn dọgbọn gba foonu lọwọ baba naa, wọn gbe redio kekere to maa n gbọ kuro lẹgbẹẹ rẹ, wọn ko si jẹ ko lanfaani si tẹlifisan rara ki wọn ma baa gbọ iroyin naa lojiji.

Titi to fi di aarọ ọjọ Aiku, Sannde, ni wọn fi iroyin yii pamọ fun awọn arugbo mejeeji yii, ṣugbọn nigba to di nnkan bii aago mọkanla kọja iṣẹgun mẹẹẹdogun ni ọkan lara awọn ẹgbọn Odumakin lọọ gbe iranṣẹ Ọlọrun agbalagba kan ninu ilu naa, Pasitọ Olu Adeyinka, wa sibẹ.

Lẹyin ọpọlọpọ iwaasu, wọn bẹ iroyin naa fun Alagba Ezekiel Abioye Odumakin pe ọkan pataki lara awọn ọmọ rẹ, Peter Yinka Odumakin, ti faye silẹ.

Baba yii kigbe kikoro, gbogbo awọn ti wọn wa lẹgbẹẹ rẹ si n sọrọ itunu fun un, lẹyin naa ni wọn tun kọja sinu yara ti iya rẹ, Alice Odumakin, sun si, ko si si ẹni to wa nibẹ ti ko bomi loju nitori iya naa barajẹ pupọ.

Latigba naa si lawọn araadugbo atawọn mọlẹbi ti n wọ lọ sinu ile naa lati lọ ba wọn kẹdun ọmọ wọn.

Leave a Reply