Awọn obinrin to wa ni abule kan ti wọn n pe ni Okemiri, niluu Oro, nipinlẹ Kwara, ti pariwo lọ sọ́dọ̀ Kábíyèsí ilu naa pe awọn ko fẹ awọn Fulani darandaran ti wọn sa wa sọ́dọ̀ awọn lati ilu Igangan àtàwọn ti wọn ti wa niluu naa tẹlẹ mọ.
Ninu Fodio kan to gba ori ẹrọ ayelujara kan ni wọn ti fi Ẹdun ọkan wọn han.
Wọn ni níṣẹ́ ni awọn Fulani darandaran yii n fi maaluu jẹ oko awọn. Okan ninu awọn àgbẹ̀ abule naa, Arabinrin Theresa Omipidan, to gba ẹnu awọn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ sọrọ ṣàlàyé pe gbogbo oko kaṣu tawọn gbin ni wọn n bájẹ́, ti wọn ko si jẹ ki awọn ri ere oko awọn jẹ.
Iya naa ni ọkan ninu awọn Fulani Bororo yii fẹ́ẹ́ ge apa ẹni kan ninu ọọdẹ oun, ṣugbon ọ̀pá to na si wọn ni ada naa ko fi ge e lọwọ, to jẹ ọ̀pá lo ba.
O fi kun un pe gbogbo kaṣu ti ọmọ oun gbin ni awọn Fulani yii ge lori lọ, ti wọn si ba a jẹ patapata.
Abilekọ Omipidan ni awọn obinrin abule yii ti lọọ ba Kábíyèsí ilu naa, awọn si ti ṣalaye pe awọn ko fẹ Bororo mọ niluu awọn. Àtàwọn ti wọn ti wa níbẹ̀ tẹlẹ, àtàwọn ti wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ de, ki gbogbo wọn maa lo.
Nigba ti ẹni to n beere ọrọ lọwọ wọn ninu fidio naa beere iha ti ọba ilu Oro kọ si ohun ti wọn n fẹ yii, awọn eeyan naa ni Kábíyèsí ti ni ki wọn maa lọ, nitori ohun ti awọn ba ti fẹ loun naa fara mọ.
Awọn obinrin yii fi kun un pe bi awọn eeyan naa ba kọ ti wọn ko lọ̣, gbogbo obinrin to wa ninu ilu naa, atọmọde ni, atagba ni lo maa filu silẹ. Wọn ni awọn ti di ẹru awọn, awọn ko si fọrọ naa ṣere rara.