Awọn ọdẹ dara pọ mọ awọn to n ṣewọde SARS l’Ọṣun, wọn lawọn yoo pese aabo fun wọn

Florence Babaṣọla

Pẹlu bi iwọde ta ko SARS ṣe n tẹsiwaju kaakiri orileede yii, awọn ẹgbẹ ọdẹ nipinlẹ Ọṣun ti darapọ mọ awọn ọdọ to n fẹhonu han naa, wọn si fi atilẹyin wọn han si nnkan ti wọn n beere fun, wọn ni ṣe ni kijọba mu atunṣe nla ba ileeṣẹ ọlọpaa lapapọ.

Lasiko ti awọn ọdẹ ọhun, labẹ Hunters Guild of Nigeria, darapọ mọ awọn ọdọ lorita Ọlaiya, lọsan-an ọjọ Isegun, Tusidee, ọsẹ yii, niluu Oṣogbo, ni wọn sọ pe lati le ṣẹru ba awọn janduku ti wọn le fẹẹ sọ awọn to n ṣewọde ọhun lẹnu lawọn ṣe wa.

Alaga wọn, Nurein Hameed, sọ pe awọn yoo maa lọ kaakiri agbegbe to wa niluu Oṣogbo lati dẹkun awọn janduku ti wọn n fi EndSars boju ja awọn araalu lole.

Husein bu ẹnu atẹ lu bi awọn kan ṣe kọ lu Gomina Oyetọla lọjọ Abamẹta, Ṣatide, to kọja, o ni awọn yoo gbiyanju lati ṣawari awọn ti wọn huwa naa, awọn yoo si fa wọn le agbofinro lọwọ.

Leave a Reply