Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ọkan lara awọn afurasi ajinigbe to ji eeyan mẹjọ gbe nibi ayẹyẹ isinku kan laipẹ yii ni Itapaji-Ekiti, lawọn ọdẹ ibilẹ ti pa.
Lasiko ija buruku kan to waye ninu igbo kan ni Eruku, ninu igbo kan to wa ni aala ipinlẹ Kwara ati Ekiti, lo ti waye ni kete tawọn ajinigbe naa ṣẹṣẹ gbowo tan lọwọ awọn mọlẹbi Fulani kan ti wọn ji gbe ni agbegbe naa.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣalaye pe ija ajaku akata lo ṣẹlẹ laarin awọn ṣọja, ọlọpaa ati awọn ajinigbe yii. Asiko naa ni wọn fi ibọn ran ọkan ninu wọn sọrun, ti awọn yooku si fi ẹsẹ fẹ ẹ.
O ni awọn ọdẹ ibilẹ yii jẹ Fulani ti wọn n pe orukọ wọn ni “Yan Banga.” Seriki awọn Fulani nipinlẹ Ekiti, Alhaji Adamu Abashe, la gbọ pe o ko wọn jọ, ti wọn si tọpinpin awọn ajinigbe naa lọ si inu igbo naa.
ALAROYE gbọ pe niṣe lawọn ọdẹ ibilẹ yii pẹlu awọn ṣọja kọkọ sapamọ sitosi ibi ti awọn ajinigbe naa ti fẹẹ gba miliọnu meji ataabọ Naira lori ọkunrin Fulani kan ti wọn ji gbe ni agbegbe naa.
Wọn ṣalaye pe ni kete ti wọn gba owo yii tan ni awọn ọdẹ ibilẹ yii atawọn ṣọja pẹlu ọlọpaa bẹrẹ si i yinbọn si wọn, ṣugbọn nigba ti ina ibọn naa pọ laarin awọn mejeeji ni awọn ṣọja ati ọlọpaa sa pada, ṣugbọn awọn ọdẹ ibilẹ yii ko pada.
Lẹyin wakati diẹ ni awọn ọlọdẹ naa pa ọkan lara awọn ajinigbe naa.
O ṣalaye pe ibọn ba ajinigbe yii lẹyin ti wọn tọpinpin wọn bii kilomita aimọye ninu igbo naa.
O ni ajinigbe ti wọn pa yii jẹ ọkan ninu awọn to ti n da gbegbe ijọba ibilẹ Ikọle ati Ayebode-Ekiti laamu lati bii oṣu mẹta sẹyin.
Ẹnikan to ba ALAROYE sọrọ ni Itapaji-Ekiti, sọ pe awọn ọlọpaa ni wọn yọnda oku ajinigbe naa fun ni kete ti wọn gbe e jade ninu igbo naa.
O ṣalaye pe ibọn AK 47 ati ẹgbẹrun lọna igba Naira ni wọn ba ninu apo ajinigbe naa.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Kọmiṣanna ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Tunde Mobayọ, sọ pe oku ajinigbe naa ati ẹsibiiti ti wọn gba lọwọ rẹ ni ti wa lọdọ awọn ọlọpaa, nigba ti awọn ẹṣọ naa n tẹsiwaju ninu itọpinpin wọn.
Kọmiṣanna yii fi kun un pe awọn ọdẹ ibile naa tun gba awọn meji silẹ lọwọ awọn ajinigbe naa, nigba ti iwadii si n tẹsiwaju lati mu awọn yooku.