Laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ni awọn ọdọ kan kora wọn jọ pẹlu akọle oriṣiiriṣii lọwọ, ti wọn si n fẹhonu han pe awọn ko fẹ SARS mọ. Iyẹn awọn ọlọpaa ti ijọba apapọ gbe kalẹ lati gbogun ti idigunjale atawọn to n lu jibiti.
Awọn ọdọ yii ni ipakupa ti awọn agbofinro naa n pa awọn ọdọ ti pọ ju. Ọpọlọpọ ẹmi alaiṣẹ ni wọn ti fi ṣofo, ti wọn ko si dawọ iwa yii duro di bi a ṣe n sọ yii.
Oriṣiiriṣii akọle ni awọn eeyan naa gbe lọwọ, leyii ti diẹ ninu wọn ka pe:’A ko fẹ SARS mọ, ẹ pada sibi tẹ ẹ ti wa’, ‘Awọn SARS ti fẹẹ pa wa tan o’, ‘Apaayan lawọn SARS, wọn buru ju adigunjale lọ ati bẹẹ beẹ lọ.
Agbegbe olu ileeṣẹ awọn ọlọpaa to wa niluu Ikẹja ni wọn gbe iwọde naa gba. Bi wọn ṣe n lọ ni wọn n pariwo pe opin gbọdọ de ba awọn SARS.
Otito nio . Afiki ijoba fo opin si SARS