Awọn ọdọ ṣewọde ‘June 12’ l’Ọjọta, lawọn ọlọpaa ba kọ lu wọn

Faith Adebọla, Eko

Paroparo ni ọpọ agbegbe da niluu Eko, pẹlu bawọn araalu ṣe fidi mọle nitori ibẹru, layajọ ayẹyẹ ‘June 12’ to waye lọjọ Abamẹta, Satide.

Lawọn ibi ti ikọ ALAROYE de, ọrọ ko yatọ tori gbọin gbọin lawọn ọlọja tilẹkun ṣọọbu wọn, awọn oniworobo naa ko patẹ ọja, bẹẹ lọpọ awọn onimọto ko ṣiṣẹ, awọn onileeṣẹ si ti ilẹkun ọfiisi wọn pa.

ALAROYE jade sigboro, lati agbegbe Iju/Ishaga si Fagba, Ikẹja si Ketu/Mile 12, Agege si Abule Ẹgba, titi marosẹ Sango lọọ de Oshodi ati ọna marosẹ to lọ si Apapa, niṣe lawọn eeyan fidi mọle wọn, iwọnba awọn diẹ ni wọn rin lẹgbẹẹgbẹ titi, awọn ọlọja ko patẹ ọja wọn, ko si si witiwiti ero gẹgẹ bo ṣe maa n ri, paapaa lọjọ Satide, tawọn eeyan fẹran lati ṣe kara-kata opin ọsẹ.

Bakan naa ni ko si ibi ti wọn ti dana ariya, awọn ọlọkada paapaa ko ṣiṣẹ, awọn kọọkan la pade lọna, eyi to pọ ju lara wọn lo wa lawọn ibudokọ ati ikorita gbogbo ti wọn n wa ero, ṣugbọn ko sẹnikan, bẹẹ lọpọ fidi mọle, ti wọn ko tilẹ jade sigboro rara.

Yatọ si fifidi mọle, wamuwamu lawọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ agbofinro duro kaakiri awọn opopona atawọn ibi tero maa n pọ si, titi kan awọn ikorita, abẹ biriiji, atawọn ibi ti wọn foju sun pe o ṣee ṣe ki ikorajọ fẹẹ ṣẹlẹ. Awọn ọlọpaa naa ko wule wa lojufo nikan, gbogbo wọn ni wọn dihamọra gidi, ti wọn so awọn agolo afẹfẹ tajutaju mọra, pẹlu ibọn lọwọ wọn, bẹẹ lawọn ọkọ ọlọpaa, ọkọ akọtami, ọkọ ayinbọn-yipo ati mọto ti wọn fi n ko awọn ọdaran tawọn eleebo n pe ni black maria, loriṣiiriṣii lo wa nikalẹ.

Amọ ṣa, ni agbegbe Ọjọta, ọrọ naa yatọ. Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa wa nikalẹ, to si fẹrẹ jẹ agbegbe yii lawọn agbofinro naa pọ si ju lọ lawọn ibi ta a de, sibẹ, awọn ọdọ kora jọ sori titi marosẹ, wọn n ṣewọde, wọn gbe oriṣiiriṣii akọle lọwọ, bẹẹ ni wọn n kọrin ọkan-o-jọkan lati fi aidunnu wọn han si ijọba to wa lode yii.

Lara akọle ti wọn gbe dani ka pe “Dandan ni ki Buhari lọ,” “Araalu para-pọ, inira yii gbọdọ dopin bayii,” ati “Ko si ina ẹlẹntiriiki, ko somi, ko si nnkan amayedẹrun, ijọba yii gbọdọ dopin”.

Bawọn ọdọ naa ṣe n kọrin ni wọn n tẹsiwaju, ṣugbọn bo ṣe ku diẹ ki wọn de iwaju ọgba Gani Fawẹhinmi Park, nibi ti wọn lawọn fẹẹ lo lati fẹhonu han, awọn ọlọpaa bẹrẹ si i yin afẹfẹ tajutaju lu wọn, wọn si tun yinbọn soke, lawọn ọdọ naa ba bẹrẹ si i sa kijokijo.

Nibi tawọn ọdọ naa ti n sa lawọn ọlọpaa ti gba fi ya wọn, wọn si mu awọn meloo kan lara wọn, wọn wọ wọn lọ sibi ti ọkọ ti wọn fi n ko ọdaran wa, bo tilẹ jẹ pe lẹyin iṣẹju diẹ, wọn tu wọn silẹ pe ki wọn maa lọ.

Eyi lo tu ikorajọ awọn ọdọ naa ka, bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn olugbe agbegbe naa ṣi kora jọ siwaju ile wọn lati woran, awọn mi-in si n sa fun afẹfẹ tajutaju ati ibọn tawọn ọlọpaa n yin leralera.

Ọkan lara awọn ti wọn tu silẹ naa fẹsun kan awọn ọlọpaa pe wọn ja foonu gba lọwọ oun nigba ti wọn fẹẹ mu oun, ṣugbọn nigba toun beere foonu naa, wọn lawọn ko ri i mọ.

Leave a Reply