Awọn ọdọ ṣewọde lọ sileejọba n’Ibadan, nitori Ọpẹyẹmi ti wọn ni ẹṣọ Amọtẹkun pa

Jọkẹ Amọri

Titi di asiko ta a fi pari iroyin yii ni awọn ọdọ ti ko niye fi rọ di sẹkiteriati ijọba to wa l’Agodi, niluu Ibadan, bẹẹ ni wọn di gbogbo awọn ọna to wa ni gbogbo agbegbe naa pa, ti wọn si ni awọn ko ni i kuro nibẹ, afi ti awọn ba foju kan Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lati ṣalaye bi ọkan ninu awọn ẹṣọ Amọtẹkun ṣe pa ọmọkunrin ti wọn n pe ni Ọpẹyẹmi laduugbo Mọkọla, niluu Ibadan.

Niṣe ni awọn ọdọ naa ti wọn pọ niye kọkọ gbe oku ọmọkunrin ti wọn pe lẹni ọdun mẹtadinlogun naa sori kẹkẹ Marwa, ti wọn si ni afi ki Gomina Makinde ṣawari Amọtẹkun to pa ọmọkunrin yii.

Ọkan ninu awọn ọdọ naa ṣalaye fun akọroyin wa pe ounjẹ ni ọmọkunrin to n kọṣe iwe titẹ naa lọọ ra ni agbegbe Uncle Joe, ni Mọkọla, niluu Ibadan, ti ọkan ninu awọn ẹṣọ Amọtẹkun fi yinbọn fun un, ti wọn ni adigunjale ni.

Eyi lo bi awọn ọdọ naa ninu ti wọn fi gbe oku Ọpẹyẹmi, ti wọn si kọri si ileeṣẹ ijọba ni Sekiteriati, wọn ni afi ki awọn foju kan Seyi Makinde, ki gomina yii si mu ọkan ninu awọn Amọtẹkun to yinbọn pa ọmọkunrin alaiṣẹ yii sita.

Niṣe ni wọn di gbogbo ọna to wọ Agodi yii pa, ti wọn si dana taya soju ọna. Igbesẹ awọn to n fẹhonu han yii da sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ ọkọ silẹ, ti awọn ti wọn fẹẹ kọja paapaa ko rọna lọ.

Bo tilẹ jẹ pe Oludamọran gomina lori eto aabo, Ọgbẹni Sunday Odukọya, rọ awọn ọdọ naa lati ṣe suuru, sibẹ wọn ni awọn ko ni i gba afi ti awọn ba foju kan gomina.

Leave a Reply