Awọn ọdọ APC binu tilẹkun ile ẹgbẹ pa ni Kwara, wọn lawọn o ri ere ijọba jẹ 

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Awọn ọdọ ẹgbẹ oṣelu APC ni Wọọdu Ajikobi, nijọba ibilẹ Iwọ Oorun Ilọrin (West), nipinlẹ Kwara, labẹ alaga wọn, Malam Dauda, yari patapata, niṣe ni wọn tilẹkun ile ẹgbẹ wọn pa, wọn lawọn o ri ere ijọba jẹ.

Ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii ni awọn ọdọ ti inu n bi ninu ẹgbẹ naa ni Wọọdu Ajikobi faake kọri, ti wọn ni ko si ẹnikẹni ti yoo ni anfaani lati wọ ile ẹgbẹ naa mọ, ayafi ti Gomina Abdulrahman Abdulrasaq ati alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kwara, Abdullahi Samari, ba yọju si awọn ni ile ẹgbẹ naa yoo to di ṣiṣi pada.

Awọn ọdọ ti ALAROYE fọrọ wa lẹnu wo sọ pe gbogbo awọn olugbe Wọọdu Ajikobi ko ri ere ijọba jẹ latigba ti Gomina Abdulrasaq ti gori aleefa. Bo tilẹ jẹ pe oniruuru ileri lo ti ṣe, ṣugbọn ko mu ọkankan ṣe ninu gbogbo ileri rẹ.

Lara awọn ileri ti gomina ṣe ni ipeṣe ibudo idanilẹkọọ iṣẹ ọwọ (Vocational Center), ṣiṣe ọna to daa, kanga-dẹrọ ati awọn nnkan amayedẹrun miiran, ṣugbọn gomina ko mu ọkankan sa loogun ninu gbogbo ẹ. Awọn ọdọ ọhun sọ pe emeeji ọtọọtọ lawọn ti lọọ ba a, sugbọn ko seso rere.

Ni bayii, awọn ọdọ naa ti waa sọ pe bi gomina ko ba waa ṣalaye ara rẹ tabi ki alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kwara  wa, awọn o ni ṣi ile ẹgbẹ.

Leave a Reply